Ọmọ gidi ni Davido, ìtẹríba rẹ̀ kò láfiwé - Ayéfẹ́lẹ́ - IROYIN AWIKONKO

YÀJÓ-YÀJÓ
Wednesday, November 3, 2021

Ọmọ gidi ni Davido, ìtẹríba rẹ̀ kò láfiwé - Ayéfẹ́lẹ́


Gbajugba olorin igbagbọ nni, Ọmọwe Ọlayinka Ayefẹlẹ ti ṣapejuwe ilu mọn-ọn-ka olorin takasufe nni, David Adeleke ti ọpọ awọn eeyan mọ si Davido gẹgẹ bi ẹni to ni itẹriba ati ibọwọfagba.

Ayefẹlẹ lo sọrọ yii lori ikanni ayelujara ti fesibuuku rẹ lanaa, ọjọ Iṣẹgun, Tuside, to si loun nifẹẹ gidigidi.

Oludasilẹ ileeṣẹ redio Fresh FM Nigeria naa sọ pe oun wa agbegbe kan, nibẹ ni Davido ti ri oun lati ọọkan, to si sare wa ba oun lati ki oun.

O ni kii ṣe pe oun ri Davido tẹlẹ, ṣugbọn bo ṣe ri oun, lo ti sare wa, to si n pariwo 'dadi mi'.

Ayefẹlẹ wa sọ pe iwa ti Davido wu naa tun jẹ koun nifẹẹ re sii kọja ti tẹlẹ, nitori pe o yatọ si wọn.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI