Ràṣídì tó n fí ìmúra Fúlàní darandaran jalè l'Abẹ́òkúta ti há o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, November 26, 2021

Ràṣídì tó n fí ìmúra Fúlàní darandaran jalè l'Abẹ́òkúta ti há o


Kani gendekunrin kan tọjọ ori rẹ ko tii ju ọmọ ọdun mejilelogun lọ mọ pe ọwọ yoo pada tẹ oun ni, boya ki ba ti jawọ kuro ninu iwa idigujale to yan laayo.


Ọjọru, Wẹside to kọja yii lọwọ tẹ Biọdun Rasheed lagbegbe Mile 6 to wa loju ọna Ajebọ, nilu Abẹokuta, ẹni ti wọn lo n mura bi Fulani darandaran lati ja awọn araalu lole.

Nnkan bi aago mẹta aabọ oru la gbọ pe Rasheed ati awọn ọrẹ rẹ lọ si adugbo yii, ti wọn si ji oriṣiriṣi dukia nibẹ. Akooko ti wọn fẹ aa salọ la gbọ pe awọn eeyan ri wọn, ti wọn si le wọn mu.

Rasheed nikan la gbọ pe ọwọ palaba rẹ segi ninu awọn yooku, ti wọn si lọ fa a le awọn ọlọpaa Kemta lọwọ

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI