Tanka epo tó fẹ̀mí àwọn èèyàn ṣòfò dànù l'Abẹ́òkúta, Gómìnà Abíọ́dún ti sọ̀rọ̀ o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, November 29, 2021

Tanka epo tó fẹ̀mí àwọn èèyàn ṣòfò dànù l'Abẹ́òkúta, Gómìnà Abíọ́dún ti sọ̀rọ̀ o


Ọjọ manigbagbe lọjọ Aiku, Sannde ana, iyẹn ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kọkanla, ọdun 2021 tun jẹ niluu Abẹokuta pẹlu bi ijamba ina tanka epo to ṣubu lulẹ lagbegbe Lafẹnwa ṣe fẹmi awọn ti ko din ni meji ṣofo danu.

Gomina Dapọ Abiọdun tipinlẹ Ogun nigba to n sọrọ bawọn mọlẹbi awọn ko fara kaaṣa ijamba naa kẹdun sọ pe ibanujẹ nla lo jẹ fun wọn.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin gomina, Ọgbẹni Kunle Ṣomọrin fi sita lorukọ gomina sọ pe ojiji ni iroyin ijamba naa ba oun, to si ba oun lọkan jẹ gidi.

O sọ pe lara idi ti wọn fi n ṣe oju ọna Lanfenwa, Rounda si Ayetoro ni lati dena iru ijamba bayii
 
Bẹẹ lo ṣeleri wi pe ijọba yoo gbe ajoku tanka epo atawọn nnkan to le ṣokunfa igbokegbodo ọkọ lagbegbe yii kuro lọna laipẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI