Tóyìn Agbọ́ládé, gbajúgbajà akọ̀ròyìn ló n ṣe ọjọ́-ìbí lónìí, ọjó kejìlélógún, oṣù kọkànlá - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, November 22, 2021

Tóyìn Agbọ́ládé, gbajúgbajà akọ̀ròyìn ló n ṣe ọjọ́-ìbí lónìí, ọjó kejìlélógún, oṣù kọkànlá


Gbogbo ọjọ kejilelogun, oṣu kọkanla ọdun ni ayajọ ayẹyẹ ọjọ ti wọn bi gbajugbaja akọroyin nni, Arabinrin Toyin Agbọlade, ẹni tọpọ awọn eeyan mọ si Irọn Lady.

Lagboole akọroyin lorilẹ-ede Naijiria, paapaa nipinlẹ Eko ati Ogun, odu ni Toyin Elizabeth Agbọlade, Olootu-binrin {Woman Editor} Iwe iroyin Yoruba nni, ALARIYA OODUA, kii ṣaimọ foloko.

Agbọlade,, ẹni to tun jẹ ọkan lara awọn ololufẹ IROYIN AWIKONKO la gbọ pe awọn ololufẹ rẹ ti n fi atẹjiṣẹ ati ẹbun oriṣiriṣi ranṣẹ sii lati nnkan bi ọsẹ meji sẹyin  ti ọjọ ibi rẹ ti n bọ lọna.

Bi ọpọ awọn eeyan lagbaye ṣe n ba Toyin Agbọlade yọ ayọ ọjọ ibi rẹ, naa ni gbogbo awọn alaṣẹ ati oṣiṣẹ ileeṣẹ AWIKONKO MEDIA CHANNEL to n gbe iroyin AWIKONKO jade naa n ki akikanju akọroyin yii ku oriire.

Adura wa ni pe wa a ṣe ọpọ ọdun laye ninu ọla nla, ninu irọrun, ifọkanbalẹ ati oore ọfẹ Ọlọrun ti ko wọpọ. Amin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI