12/12: Tunbọsun Ọdunsi, agba oṣere nni fẹẹ gba ọkọ bọginni l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, December 5, 2021

12/12: Tunbọsun Ọdunsi, agba oṣere nni fẹẹ gba ọkọ bọginni l'Abẹokuta


Gbogbo eto lo ti pari patapata fun ogbontarigi ati agba oṣere tiata nni, Alagba Tunbọsun Ọdunsi lati gba ọkọ ayọkẹlẹ bọginni, ti awọn ololufẹ rẹ fẹẹ fi ta a lọrẹ lọjọ Aiku, Ṣannde to n bọ yii, iyẹn ọjọ kejila, oṣu kejila ti a wa yii.
 
Ọkan pataki lara awọn ilu mọ-n-ka sọ sọrọsọrọ agbaye, Kọlawọle Atanda Adejojo, ẹni tawọn ololufẹ rẹ mọ si Kasnaty Sugar la gbọ pe o ṣagbatẹru bi Alagba Tunbọsun Ọdunsi ṣe fẹẹ gba ẹbun mọto boginni ọhun ti owo rẹ ko din ni miliọnu meji naira.

AWIKONKO gbọ pe ọjọ naa gan-an ni Kasnaty fẹẹ ṣọdun pẹlu awọn arugbo ti ko din ni igba, ti yoo si tun fi ẹbun ọdun ta wọn lọrẹ. Koda, a gbọ pe ọkan lara awọn arugbo yii yoo tun gba owo ti ko din lẹgbẹrun lọna igba naira lọ sile gẹgẹ bi ẹbun.

Gbọngan ayẹyẹ ti Datktad to wa lagbegbe Quarry Road nilu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun ni eto ọhun yoo ti waye, bẹrẹ lati agogo mẹrin irọlẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI