Adájọ́ àgbà mẹ́ta fẹ̀yìntì lọ́jọ́ kan ṣoṣo ní Kwara, ni Gómìnà AbdulRazaq bá tú àṣírí nlá síta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, December 21, 2021

Adájọ́ àgbà mẹ́ta fẹ̀yìntì lọ́jọ́ kan ṣoṣo ní Kwara, ni Gómìnà AbdulRazaq bá tú àṣírí nlá síta


Lọjọ Aje, Mọnde, ana ni awọn adajọ agba mẹta ọtọọtọ nipinlẹ Kwara fẹyinti lẹnu iṣẹ, lẹyin ọpọlọpọ akitiyan wọn lati rii pe eto idajọ ododo n waye lẹka eto idajọ, iyẹn latigba ti wọn ti gba iṣẹ naa.
 
Nibi eto naa, to waye nilu Ilọrin, ipinlẹ Kwara ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti sọ oriṣiriṣi ọrọ, to si jẹ ko di mimọ pe bi wọn ṣe n yan adajọ agba ko lọwọ Gomina ninu rara, bi ko ṣe pe awọn to wa ni ilana eto ofin ni wọn mọ bi nnkan ṣe n lọ si nibẹ, ati awọn ti ipo naa kan.
 
Gomina AbdulRazaq jẹ ko di mimọ nibẹ pe ijọba oun naa ti n gbe igbesẹ lori abadofin to nii ṣe pẹlu ọrọ, iyẹn Judicial Autonomy Bill, nitori pe ọrọ awọn oṣiṣẹ eto ofin ṣe pataki si oun pupọ, toun si gbọdọ wa gbogbo ọna ti wọn gbọdọ fi mọ riri ijọba.

Nibi akanṣe eto ọdun ofin ti a mọ si Legal Year fọdun 2021/2022 ti ile-ẹjọ giga ipinlẹ Kwara ṣagbatẹru rẹ ni wọn tun ti yan awọn adajọ agba tuntun miran ti yoo ṣakoso ẹka eto idajọ, bakan naa ni wọn tun gbe eto ati ilana tuntun jade.

AbdulRazaq, nigba to n sọrọ sọ pe "Mo dupẹ lọwọ ẹka eto idajọ nipinlẹ Kwara bi wọn ṣe n bẹrẹ ọdun ofin tuntun fọdun 2021/2022. Mi o ni iyemeji wi pe ọdun yii so eso rere jade. Fun awọn adajọ agba tuntun, mo kii yin daadaa. Ati si awọn to ṣẹṣẹ fẹyinti, ẹ ko ni fẹyinti sinu iku. A dupẹ gidigidi lọwọ yin fun bi ẹ ti ṣe sin ipinlẹ Kwara, Naijiria ati awọn eeyan. E ku iṣẹ takuntakun. A ṣi tun ma maa ranṣẹ pe lati wa ṣiṣẹ fun gẹgẹ bi ẹ ti n ṣe lawọn agbegbe gbogbo."

Siwaju sii lo jẹ ko di mimọ pe yiyan awọn adajọ agba kii ṣe lati ọdọ gomina tabi awọn igbimọ iṣakoso oun, ati pe bibu ọwọ lu abadofin to wa nilẹ ko di bi wọn ṣe n na owo si ẹka mẹta to di iṣakoso ijọba mu lọwọ, nitori pe gbogbo wọn lo ni iṣẹ pataki ti wọn n ṣe.
 
O tun sọ pe nigba ti iṣakoso oun de ori ipo, lara awọn nnkan toun ṣe ni titun awọn yara ti eto idajọ ti n waye ṣe, ko si le dun un wo loju, ati pe awọn n fẹ nnkan ti yoo ba ti igbalode mu.
 
Awọn adajọ agba mẹta ti wọn fẹyinti naa ni Onidajọ Mathew Adewara, Onidajọ Maria Ajibola Afọlayan, ati Onidajọ Garba Issa Babatunde.
 


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI