Àwọn apani ṣètùtù owó méje dèrò àtìmọ̀lé ọlọ́pàá l'Abẹ́òkúta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, December 1, 2021

Àwọn apani ṣètùtù owó méje dèrò àtìmọ̀lé ọlọ́pàá l'Abẹ́òkúta


Ko din ni ọkunrin meje tọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun tẹ niluu Abẹokuta laipẹ yii, iyẹn awọn ti wọn sọ pe wọn ko niṣẹ meji ju ki wọn maa paayan fi ṣetutu owo lọ nilu Abẹokuta.
 
Lekan Ọladipupọ, ẹni ọdun mejidinlogoji to n gbe labule Ṣotan; Sulaiman Arẹmu, ẹni ọgbọn ọdun to n gbe lagbegbe Imala Ẹlẹga; Ifayẹmi Madru,ọmọ ọdun mẹrinlelogun to n gbe labule Ṣotan; Shittu Saheed, ẹni ọdun mejidinlogoji to n gbe labule Alarugbo; Samọd Sulaiman, ẹni ọdun marundinlogoji to n gbe labule Ṣotan; Akanji Mọruf, ọmọ ọdun mẹtalelogoji to n gbe labule Alabata, ati Tajudeen Adekunle, ọmọ ọdun mẹrindinlogoji toun n gbe lagbegbe Ṣapon nilu Abẹokuta la gbọ pe ọwọ palaba wọn segi.
 
Ọkunrin  kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Abraham Okosun, la gbọ pe o lọ ta awọn ọlọpaa Bode Olude nilu Abẹokuta lolobo wi pe awọn kan ti ṣeku pa ẹgbọn oun, Sunday Okosun, to n gbe labule Agbara, nitosi Mawukọ.
 
Abraham sọ pe ṣe lawọn eeyan naa pa ẹgbọn oun, ti wọn si yọ ẹya ara rẹ lati fi ṣetutu owo, ko to di pe wọn lọ ku oku rẹ sinu igbo kan.
 
Eyi lo jẹ kawọn ọlọpaa dide lati ṣe iwadii, ti wọn si rii pe awọn tọwọ tẹ yii ni wọn wa nidii iwa buruku naa.
 
Lekan Ọladipupọ la gbọ pe ọwọ kọkọ tẹ, oun si lo ka gbogbo awọn ti wọn jọ ṣiṣẹ ọhun, bẹẹ lo jẹ ko di mimọ pe oun gan-an lẹni to yinbọn pa Sunday pẹlu ibọn.
 
Lekan funra rẹ lo si tu aṣiri bọwọ ṣe tẹ awọn mẹfa yooku ti wọn lọwọ si pipa Sunday
 
Ni bayii, ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankọle ti paṣẹ pe ki wọn lọ foju wọn ba ile-ẹjọ nigba ti iwadii ba tubọ pari lẹkunrẹrẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI