Nítorí ipò Balógun Ìjẹjà, agbẹjọ́rò fẹ̀sùn kan àgbà òṣìṣẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, December 4, 2021

Nítorí ipò Balógun Ìjẹjà, agbẹjọ́rò fẹ̀sùn kan àgbà òṣìṣẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn


Gbajugbaja agbẹjọro ilu Ijẹja l'Abẹokuta, Kẹhinde Amusa ti fẹsun kan ọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Reuben Olufẹmi Ṣolankẹ niwaju olori awọn oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ Ogun.
 
Ko si ẹsun meji ti a gbọ pe Amusa fi kan Ṣolankẹ, bi ko ṣe pe o sọ ara rẹ di oloye, paapaa nilu Ijẹja, eyi to lo tako ofin oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ Ogun.
 
Yatọ si eyi, Amusa sọ pe ṣe ni Ṣolankẹ n fi ipo to loun di mu gẹgẹ bi Balogun ilu Ijẹja da ilu ru, to si n ṣi ipo naa lo, ati pe kaka ko maa lo ipo naa lati fi mu idagbasoke ba ilu Ijẹja, ṣe lo fi n fa ọwọ ago idagbasoke sẹyin.
 
Ninu iwe ẹsun naa ti Amusa fi ranṣẹ si olori awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ogun, lọjọ kẹwaa, oṣu kọkanla, ọdun yii, eyi ti ẹda rẹ tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yii, ọkunrin naa sọ pe ipo Balogun Ijẹja ti Ṣolankẹ di mu tako ofin to de oṣiṣẹ ijọba.
 
Agbẹjọro naa,ẹni to jẹ ọmọ bibi ilu Ijẹja lo jẹ ka mọ pe Ṣolankẹ ṣi wa lẹnu iṣẹ ijọba, koda, to tun jẹ ko di mimọ pe bi ẹni to jokoo le ori ẹtu-ibọn ni ipo Balogun Ijẹja ti Ṣolankẹ di mu.
 
Ninu awọn ọrọ rẹ, o sọ pe ṣe ni Ṣolankẹ maa n gbe ara rẹ le ori awọn oloye yooku nilu Ijẹja, to si maa n ṣe wọn bo ṣe wu.

Bakan naa lo wa jẹ ko di mimọ pe ọkan ninu mejeeji ni ki Ṣokankẹ fọwọ mu, yala ko fi ipo Balogun ilu silẹ, ko si maa tẹsiwaju nidi iṣẹ ijọba, tabi pe ko fi iṣẹ ijọba silẹ, ko si gbajumọ oro oye ilu.

O ni didi ipo oye ilu mu lakooko teeyan wa lẹnu iṣẹ ijọba ko ba ilana iṣẹ ijọba mu, fun idi eyi, o ni ki Ṣolankẹ fi ọwọ mu ẹyọkan nibẹ.
 
"Ṣe lo maa n paṣẹ lori awọn oloye, lai wo ti awọn oloye ti ipo wọn ju tiẹ lọ, ti yoo si maa gun wọn garagara. O paṣẹ pe ki wọn lọ ge igi Aje to wa ni odo Ore tilu Ijẹja, eyi to tako iṣẹṣe ilu Ijẹja, nitori pe eewọ ni.
 
"Ṣolanke lo ṣagbatẹru bi wọn ṣe gbe ijọba ibilẹ idagbasoke ṣe gbe kikọ ọja igblode kuro nilu Ijẹja, to jẹ pe ori ilẹ Ibara ni wọn lọ kọ ọja igbalode naa si, iyẹn lasiko iṣakoso Sẹnetọ Ibikunle Amosun gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Ogun."
 
O wa rawọ ẹbẹ si olori awọn oṣiṣẹ naa lati tete gbe igbesẹ to ba yẹ lori ọrọ Reuben Olufẹmi Ṣolankẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI