Ẹ jẹ́ kí aṣọ Àdìrẹ wà lára aṣọ ilé-ìwé - Adéjọkẹ́ Ṣómóyè gbàwọn Gómìnà ilẹ̀ Yorùbá lámọ̀ràn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, December 29, 2021

Ẹ jẹ́ kí aṣọ Àdìrẹ wà lára aṣọ ilé-ìwé - Adéjọkẹ́ Ṣómóyè gbàwọn Gómìnà ilẹ̀ Yorùbá lámọ̀ràn


Alaṣẹ ati oludasilẹ ajọ kan to n ṣe igbelarugẹ Èdè, Àṣà àti Ì1q1ṣe Yorùbá, Gbegede Ẹwa Ede, Ọmọọba Adejọkẹ Ṣomoye ti gba gbogbo gomina ilẹ Yoruba lamọran lati sọ ọ di ofin pe ki aṣọ Adirẹ wa lara aṣọ ileewe lati alakọbẹrẹ titi de girama.

O ni fifi aṣọ Adirẹ kun aṣọ ileewe yoo tubọ ṣe igbelarugẹ fun aṣa ati iṣe ilẹ Yoruba pupọ.

Siwaju sii lo kọminu to si tun bu ẹnu atẹ lu bi orileede China ṣe n ko aṣọ Adirẹ ti wọn wọle si orileede yii, ti awọn eeyan si n tẹwọ gba a, eyi to n jẹ ki wọn maa pa ojulowo aṣọ Adirẹ ti sẹgbẹ kan.

Adejọkẹ Ṣomoye lo sọrọ yii nibi eto 'Irọlẹ Aṣa', eyi to fi n ṣayẹyẹ ọdun kẹwaa to da ajọ Gbagede Ẹwa Ede silẹ lati maa fi gbe Àṣà, Ìṣe ati Èdè Yorùbá, paapaa Aṣọ Adirẹ larugẹ kaakiri agbaye.

Lara awọn to wa nibi eto naa ni Gomina Dapọ Abiọdun ti Dọkita Toyin Taiwo ṣoju fun; Abẹnugọn ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, Ọnọre Ọlakunle Oluọmọ; Ọọni Ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi (Ọjaja keji) ti Ọba  Muraina Adedinni, Asoya tilu Ile-Isoya Ifẹ ṣoju fun; Olu Itori, Ọba Abdulfatai Akorede Akamọ; ati awọn miran.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI