Èyí làwọn àgba Wòlíì tí àsọtẹlẹ wọn wá sí ìmúṣẹ lọ́dún 2021 - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, December 20, 2021

Èyí làwọn àgba Wòlíì tí àsọtẹlẹ wọn wá sí ìmúṣẹ lọ́dún 2021


Bi ogbologbo ọdun 2021 ṣe n pari lọ, oriṣiriṣi lo ti ṣẹlẹ, paapaa julọ, pupọ awọn asọtẹlẹ ti awọn agba Wolii lorilẹ-ede yii, ati lagbaye gbe jade lo ti wa si imuṣẹ.
 
Eyii si la fi n ṣe agbeyẹwo diẹ lara awọn asọtẹlẹ to ti wa si imuṣẹ lọdun 2021 to n pari lọ yii, ati awọn Wolii to gbe wọn jade.
 
Lara awọn agba ati gbajugbaja Wolii ti wọn gbe asọtẹlẹ sita fun ọdun yii ni Wolii Joshua Iginla, Primate Elijah Ayodele, Wolii TB Joshua to ti doloogbe, Apọsiteli Suleiman, Wolii Odumeje, to fi mọ Apọsiteli Okikijesu.

Wolii Joshua Iginla: Alaṣẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi Champions Royal Assembly, ninu awọn asọtẹlẹ mẹrinlelọgbọn rẹ fọdun 2021 lo ti wa si imuṣẹ. Lara wọn lo si sọ nipa Biafra; awọn ọdọ; Covid-19; idibo lorilẹ-ede Zambia; ilẹ Afrika ati agbaye. Pupọ awọn asọtẹlẹ yii lo si ti wa si imuṣẹ lai fi gba kan bo ọkan ninu.

Apọsiteli Suleiman: Asọtẹlẹ ibẹru mejidinlogoji ni Apọsiteli Suleiman gbe jade fọdun 2021. Boun naa ṣe sọrọ lori ọrọ oṣelu, lo sọrọ lori oye ati ipo ọba, lagba oṣere, Covid-19, ati bẹẹbẹẹlọ. Awọn kan tiẹ dide lati ba ọkunrin naa lorukọ jẹ, eyi to mu ki ogo rẹ buyọ nipa awọn asọtẹlẹ rẹ to ṣẹlẹ.

Wolii Elijah Ayọdele: Alaṣẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi INRI Evangelical Spiritual Church, ni Wolii Elijah Ayọdele. Ọna ara ni asọtẹlẹ tirẹ si maa n gba yọ lọdọọdun, pẹlu bo ṣe jẹ gbogbo ẹka agbaye lo ti maa n gbe asọtẹlẹ rẹ sita.
 
Eyi to maa n jẹ ki asọtẹlẹ Wolii Ayọdele yatọ ni pe ki ayẹyẹ ọdun Keresimesi too de, iyẹn gbogbo ọjọ kejilelogun tabi ọjọ kẹtalelogun, oṣu kejila, ọdọọdun lo maa n gbe asọtẹlẹ rẹ fun ọdun tuntun jade. Asọtẹle tirẹ kii sii duro lori ọrọ oṣelu tabi orilẹ-ede Naijira nikan, bi ko ṣe kaakiri agbaye. Bo ṣe n nipa ọrọ oṣelu, lo n sọ nipa ere idaraya, agbo ariya, ati bẹẹbẹẹlọ.

Diẹ lara awọn asọtẹlẹ to ti wa si imuṣẹ ni ti ijinigbe; iku olori Boko Haram, Abubakar Shekau; Rukerudo nipinlẹ Kaduna; ile to wo ni Lekki, Afara to ja lulẹ lojiji; Ifẹhonu han lodi si ijọba Buhari; Wahala Fulani darandaran atawọn agbẹ; Wahala laaarin awọn aṣofin; Gbigbegidina ikanni Twitter; Wahala oṣelu nipinlẹ Imo ati Anambra; igbiyanju lati ṣeku pa gomina ipinlẹ Benue ati Borno; yiyọ awọn olori ile igbimọ aṣofin danu; Wahala ati idaamu AGF; esi idibo ipinlẹ Anambra; agbeyẹwo ofin idibo; kikọlu ijọ Ọlọrun; iku awọn aṣofin; wahala laaarin awọn gomina PDP; Korona; ati bẹẹbẹẹlọ.

Oloogbe Wolii T.B Joshua: Ọkan lara awọn Wolii tawọn eeyan kii fibẹ ko ọrọ rẹ tabi asọtẹlẹ rẹ danu ni Oloogbe T.B Joshua, to si jẹ pe asọtẹlẹ fọdun 2021 fẹẹ ruju. T.B Joshua ko sọrọ lori ohun miran to kọja ajakalẹ arun Korona ati itusilẹ omi ati ororo rẹ, eyi to ni yoo wo arun naa san.
 
Wolii T.B Joshua sọ pe oun fẹẹ ṣe agbeyẹwo awọn asọtẹlẹ rẹ daadaa ko to di pe oun gbe wọn jade, ṣugbọn ti ko pada ri wọn gbe jade ko to di pe o pada ku loṣ kẹfa, ọdun yii.

Wolii Okikijesu: Wolii yii naa ko gbẹyin ninu awọn to n duro lori asọtẹlẹ ti wọn ba gbe jade. Bo ṣe sọrọ nipa iku gomina kan, naa lo sọrọ nipa oludije sipo aarẹ lọdun 2023, wahala nile agbara orilẹ-ede yii, iyẹn Aso Rock laaarin oṣu kin-in-ni si oṣu kẹta, bo tilẹ jẹ pe puọ rẹ ni ko tii wa si imuṣẹ.
 
Lati ọwọ Ọgbẹni John Eguavoen nipinlẹ Eko

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI