Ìlú Abẹ́òkúta gbàlejò àwọn èèyàn pàtàkì-pátákí níbi ayẹyẹ ọdún ÒWÚYẸ́ ti gbajúgbajà sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀, Mákindé Fásunlé fẹ́ẹ́ ṣe - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, December 13, 2021

Ìlú Abẹ́òkúta gbàlejò àwọn èèyàn pàtàkì-pátákí níbi ayẹyẹ ọdún ÒWÚYẸ́ ti gbajúgbajà sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀, Mákindé Fásunlé fẹ́ẹ́ ṣe


Gbogbo eto lo ti pari patapata bayii fun ti ayẹyẹ ọdun OWUYE, eyi ti gbajugbaja sọrọsọrọ ori redio nni, Oloye Makinde Fasunle, ẹni tọpọ awọn eeyan mọ si Sẹnetọ Sọrọsọrọ fẹẹ ṣe lọjọ kẹrinla, oṣu kejila, ọdun 2021, iyẹn ọjọ Iṣẹgun, Tuside, ọla.

AWIKONKO gbọ pe gbọngan ile ounjẹ igbalode ti SPICES to wa ni Oke-Ilewo nilu Abẹokuta leto ọhun ti fẹẹ waye, bẹrẹ lati agogo mejila ọsan.

Ọdun OWUYẸ la gbọ pe Oloye Makinde Fasunle fi n mọ riri awọn ololufẹ rẹ lori eto OWUYẸ to n ṣe nile iṣẹ redio Fresh FM to wa nilu Abẹokuta.

Ayẹyẹ tọdun yii la gbọ pe o fẹẹ gbọna ara yọ, pẹlu bi ọkunrin naa ṣe fẹẹ fun awọn ti ko din ni ọgbọn ni awọọdu fun bi wọn ṣe n ṣagbatẹru naa loore-koore.

Nibẹ lo tun ti fẹẹ ṣe eto ikiwojọ fun gbọngan ile igbohunsafẹfẹ to n kọ lọwọ, eyi to ku miliọnu meje naira ki owo ọhun pe.

Lara awọn ti yoo gba awọọdu lọjọ naa ni: Alaaja Wasilat Akiode, alaṣẹ omi Kaslat; Alaaji Isiaka Kokumo, alaṣẹ Sharpman Bitters; Oloye Oluranti Akinbo; Arabinrin Lawal; Oloye Ṣọla Adekọya, Yeye Oge ilu Ọgba; Oloye Adeniyi Samsondeen, alaṣẹ otẹẹli Oṣupa atawọn mi in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI