Aláàfin Ọ̀yọ́ báwọn ọmọ ìlú Ìbàdàn kẹ́dùn ikú Ọba Adétúnjí tó wàjà - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, January 4, 2022

Aláàfin Ọ̀yọ́ báwọn ọmọ ìlú Ìbàdàn kẹ́dùn ikú Ọba Adétúnjí tó wàjà


Alaafin Ọyọ, Iku Baba Yeye, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi kẹta ti ba gbogbo ọmọ ati olugbe ilu Ibadan kẹdun ipapoda ọba wọn, Ọba Saliu Adetunji to waja lọjọ Aiku, Sannde to kọja yii.

Ninu atẹjade ti Ọgbẹni Ọladọtun Ọladele, ẹni to jẹ alakoso fọrọ eto iroyin ori ayelujara fi sita lorukọ Alaafin, o ni oun ko le ṣai ba gbogbo ọmọ Ibadan kẹdun, nitori pe adanu nla lo jẹ, ati pe asiko ti wọn nilo Kabiyesi wọn julọ ni awọn baba nla rẹ pe e sọdọ.

Alaafin, ẹni to jẹ alaga ẹgbẹ awọn ọba alaye nipinlẹ Ọyọ, sọ pe oun n ba ilu Ibadan kẹdun lorukọ igbimọ awọn ọba, afọbajẹ, Ọmọọba, Ọmọọbabinrin, awọn oloye, ati gbogbo ọmọ ipinlẹ Ọyọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI