Àṣírí ẹnìkan ṣoṣo tó lè gba Sunday Ìgbòho sílẹ̀ láhàámọ́ tó wà lu síta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, January 2, 2022

Àṣírí ẹnìkan ṣoṣo tó lè gba Sunday Ìgbòho sílẹ̀ láhàámọ́ tó wà lu síta


Iroyin to tẹ wa lọwọ bayii ti fidi rẹ mulẹ wi pe ẹnikan ṣoṣo to le tu olori ajijangbara ilẹ Yoruba, Oloye Sunday Adeniyi Adeyẹmọ silẹ lahamọ to wa ni Aarẹ ilẹ olominira Bẹnin, Patrice Talon.

Ọjọ kin-ni-in, oṣu keje, ọdun to kọja ni wọn mu Oloye Sunday Adeyẹmọ, Igboho lakooko to fẹẹ wọ baluu lọ si orileede Germany, nibi to ti ni iwe igbelu.

Ọgbẹni Ọlayọmi Koiki nigba to n sọrọ jẹ ko di mimọ pe ko sẹni meji to tun le gba Igboho silẹ kuro lahaamọ to wa, to kọja Aarẹ Talon, nitori pe oun nikan lo laṣẹ.
 
Gẹgẹ bi ẹ ṣe mọ pe oṣuu kẹfa ree ti Igboho ti wa lahaamọ naa, latigba ti wọn ti mu.

Koiki sọ pe ọna ti wọn gba pa Oloogbe MKO Abiọla, Funshọ Williams ree, ti wọn si fẹ pa wọn lọna ti ko ba ofin mu.
 
Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe gbogbo ọna tawọn mọ lati le jẹ ki wọn fi Igboho lo ti ja si pabo fun wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI