Ẹ wo ẹni ipò Olúbàdàn kan báyìí - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, January 2, 2022

Ẹ wo ẹni ipò Olúbàdàn kan báyìí


Ẹlẹkun n sunkun, alayọ n yọ, bẹẹ gẹlẹ lọrọ to wa nilẹ yii jẹ lori ipo Olubadan tilẹ Ibadan, nipinlẹ Ọyọ.

Latigba ti iroyin ipapoda Olubadan, Ọba Saliu Adetunji ti jade sita laaarọ oni, ọjọ Aiku, Sannde lawọn mọlẹbi Kabiyesi ati awọn to sunmọ aafin ti bẹrẹ sii barajẹ.

Koda, nigba ti awọn oniṣegun oyinbo ti Kabiyesi ku sọdọ wọn gbe oku rẹ wọ aafin lawọn ti bẹrẹ sii gbe ara wọn ṣanlẹ.

Nibi awọn mọlẹbi Ọba Adetunji ti n barajẹ, lawọn mọlẹbi ti ipo naa kan ti bẹrẹ ajọyọ ti wọn, wi pe awọn naa yoo de ipo yii.

Sẹnetọ Lekan Balogun, ẹni ọdun mọkandinlọgọrin ni ipo Olubadan kan bayii, gẹgẹ bi ohun ti a gbọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI