Lẹ́yìn ọdún márùn-ún lórí ìtẹ́, Ọba Adétúnjí, Olúbàdàn wàjà lójijì - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, January 2, 2022

Lẹ́yìn ọdún márùn-ún lórí ìtẹ́, Ọba Adétúnjí, Olúbàdàn wàjà lójijì


Iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yii ti jẹ ko di mimọ pe Olubadan tilẹ Ibadan, Ọba Saliu Adetunji, Aje Ogungunnisọ kin-in-ni ti waja lẹni ọdun mẹtalelaadọrun-un.

A gbọ pe aarọ oni, ọjọ keji, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022 ni Ọba Adetunji gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra, to si lọ ba awọn baba-nla rẹ.

Ọjọ kẹrin, oṣu kẹta, ọdun 2016 ni Ọba Saliu Adetunji gba ọpa aṣẹ ati ade gẹgẹ bi Olubadan tilẹ Ibadan tuntun, lẹyin ipapoda Ọba Odulana Ọdungade kin-in-ni.

AWIKONKO gbọ pe ọsibitu UCH to wa nilu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ ni kabiyesi ku si lẹyin aisan rampẹ, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Ẹkunrẹrẹ iroyin naa n bọ laipẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI