Ogun to n dena ajakalẹ arun Korona ti pọ kaakiri ipinlẹ Ogun - Ijọba - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, January 29, 2022

Ogun to n dena ajakalẹ arun Korona ti pọ kaakiri ipinlẹ Ogun - Ijọba

 
Ijọba ipinlẹ Ogun labẹ Gomina Dapọ Abiọdun ti sọ pe ogun to n dena ajakalẹ arun korona, iyẹn AstraZeneca ti wa lọpọ yanturu kaakiri ibudo eleto ilera ayasọtọ to wa nipinlẹ naa.
 
Kọmiṣanna fọrọ eto ilera nipinlẹ naa, Dọkita Tomi Coker lo sọ eyi di mimọ lakooko to n bawọn akọroyin ijọba sọrọ nilu Abẹokuta, to si ni ogun yii ni ipele keji fawọn to ti gba ti alakọkọ.
 
O lawọn ti ko ba tii gba ogun yii ki wọn tete lọ si awọn ibudo eto ilera ti wọn ya sọtọ fun gbigba ogun yii, lati gba a ko to di pe o tan.
 
O ni ẹgbẹrun ẹgbẹrun lọna igba ataabọ le diẹ{255,000} ti AstraZeneca, ẹgbẹrun lọna ọgọfa {120,000} ti Pfizer, ati ẹgbẹrun mejilelọgbọn {32,000} ti Moderna vaccine lawọn ti tẹwọ gba lati okeere wọle sipinlẹ Ogun.
 
Coker sọ siwaju pe oun ti bẹrẹ igbesẹ pẹlu awọn alẹnulọrọ, olori agbegbe lati ṣe ipolongo naa fawọn eeyan wọn lati tete lọ gba ogun to n dena ajakalẹ arun ọhun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI