Ọọ̀ni Ilé-Ifẹ̀ fẹ́ẹ́ dá Wòlíì Ayọ̀délé lọ́lá lọ́jọ́ àyájọ́ olólùfẹ́ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, January 27, 2022

Ọọ̀ni Ilé-Ifẹ̀ fẹ́ẹ́ dá Wòlíì Ayọ̀délé lọ́lá lọ́jọ́ àyájọ́ olólùfẹ́Gbogbo eto lo ti fẹẹ pari bayii fun akanṣe eto ọlọdọọdun ti Wolii Elijah Babatunde Ayọdele, alaṣẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi INRI Evangelical Spiritual Church nipinlẹ Eko maa n ṣe.
 
AWIKONKO gbọ pe gbogbo ọjọ kẹrinla, oṣu keji, ọdun ni Wolii Ayọdele maa n fi ẹmi imoore han si Ọlọrun to da ohun gbogbo.

Ọjọ naa si ni Wolii Ayọdele maa n fi ẹmi imoore han sawọn ololufẹ ati alabaṣiṣẹpọ, pẹlu awọn eeyan lawujọ, ti yoo si ro wọn lagbara lara ọtọ.
 
Eyi to fẹẹ waye lọdun yii la gbọ pe Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi fẹẹ da Wolii Ayọdele lọla nipa yiyọju sibi akanṣe isin idupẹ naa.

Ṣaaju akoko yii ni Sultan tilu Ṣokoto, Sa’adu Abubakar ti sọ pe oun yoo wa nilu Eko lati yẹ Wolii Ayọdele si, nitori pe Ọlọrun n gba ẹnu rẹ sọrọ loore-koore.

Ọpọ igba ni Ọba Adeyẹye ti fidi rẹ mulẹ wi pe Wolii Ayọdele wa lara awọn Wolii ti Ọlọrun n lo lakooko yii, ti kii sii fi igba kan bo ọkan ninu, ati pe o yatọ si awọn Wolii alatẹnujẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI