Pátá obìnrin làwọn eléyìí fi n ṣiṣẹ́ burúkú - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, January 16, 2022

Pátá obìnrin làwọn eléyìí fi n ṣiṣẹ́ burúkú


Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Delta ti tẹ awọn gendekunrin kan ti wọn le ni ogun, awọn ti a gbọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun pọmbele ni wọn.

Lara awọn nnkan ti wọn ka mọ wọn lọwọ ni pata obinrin, eyi ti wọn fi n ṣiṣẹ buruku wọn.

Yatọ si eyi, wọn tun ka ibọn onigi, egboogi oloro ti Indian Hemp ati Codeine, Razlers, ọbẹ, maṣiini ti wọn fi n lọ igbo, ẹgbẹrun mọkandinlaadọrin (₦69,000) naira ati oogun abẹnugọngọ loriṣiriṣi.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ naa, DSP Edafe Bright, ti sọ pe gbogbo wọn ni yoo foju ba ile-ẹjọ nigba ti iwadii ba pari.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI