Àrágbáyamúyamù àkànṣe iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu ní Kwara, l'AbdulRazaq bá gbàwọn agbaṣẹ́ṣe lámọ̀ràn láti jára mọ́ṣẹ́ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 4, 2022

Àrágbáyamúyamù àkànṣe iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu ní Kwara, l'AbdulRazaq bá gbàwọn agbaṣẹ́ṣe lámọ̀ràn láti jára mọ́ṣẹ́


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti gba gbogbo awọn agbaṣẹṣe lamọran lati jara mọ iṣẹ akanṣe ti wọn gbe le wọn lọwọ, lojuna lati tete pari wọn, ko si si lilo fun igbadun araalu.

Yatọ si eyi, ijọba Kwara tun gba gbogbo awọn araalu, paapaa awọn awakọ lati ṣe suuru gidigidi lawọn opopona, iyẹn bi akanṣe iṣẹ idagbasoke opopona ṣe n lọ kaakiri lọwọ.


Wọn jẹ ko di mimọ pe awọn ohun amuyẹ bii ilana lati wa ọkọ loju popona lọsan ati loru ni ijọba ti pese silẹ, ki wọn si tẹle awọn ilana ọhun.

Bakan naa nijọba tun jẹ ko ye araalu wi pe awọn oṣiṣẹ oju popona ti yoo maa dari ọkọ lọtun losi yoo wa nita lati dari ọkọ, fun idi eyi, awọn eeyan ko gbọdọ tapa si idari wọn.

Lara awọn opopona ti akanṣe iṣẹ idagbasoke opopona yoo ti maa lọ ni Osi-Obbo Aiyegunle, Ilesha Baruba Gwanara, Afara oloke ti General Tunde Idiagbon ati Yebumot – layipo (Roundabout) Adeta  – Mount Carmel. 


Awọn opopona ti yoo bẹrẹ lọsẹ to n bọ ni:

i. Reconstruction of Adeta Roundabout - Pakata Roundabout, Ilorin 

ii. Rehabilitation of Oja Roundabout - Pakata Roundabout, Ilorin 

iii. Construction of Oloje - Ita Aman Madi Road, Ilorin

iv. Tanke Oke Odo Ring Road 1.8km Ilorin 

v. Construction of Ballah Township Road (Rehabilitation of Eyenkorin to Ballah 6.2Km)

vi. Construction of General Hospital Road - Otte

vii. Construction of Ora Township Road

viii. Secretariat road to New Market Lafiagi Township, Lafiagi 

ix. Tsaragi Township Road Edu 

x. Rehabilitation of Iyana Shonga to Shonga Road, Shonga 

xi. Construction of Tsuba – central School, lade Patigi

xii. Construction of Oloje road linking Balode

xiii. Construction of Coca Cola – Palace Road, Jebba

xiv. Construction of Lanwa Township

xv. Construction of Oloru Township Road

xvi. Bani Township Road


xvii. Construction of Okuta Central Mosque Junction - Emirs Palace - Sakiyara 

xviii. Construction of Saint Clairs Junction Offa Ikotun Road

xix. Oko – Idofin – Igbana Road Rehabilitation

xx. Construction of Oke Oyi Township Road

xxi. Construction of (2x12.5) span Bridge along Bukka-Adena Road Kaiama
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI