Ẹgbẹ́ àwọn ọ̀dọ́ CAN ṣàbẹ̀wò sí Gómìnà AbdulRazaq - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, February 13, 2022

Ẹgbẹ́ àwọn ọ̀dọ́ CAN ṣàbẹ̀wò sí Gómìnà AbdulRazaq


Ẹgbẹ awọn ọdọ ẹlẹsin Kristẹni nni, labẹ aburada Youth Wing Christian Association of Nigeria (YOWICAN), ẹka tipinlẹ Kwara ti ṣe abẹwo nla si Gomina AbdulRahman AbdulRazaq, lati gbe oṣuba kare fun un lori ọna to n gba lati mu alaafia ba ipinlẹ naa.
 
Ọfiisi gomina to wa nilu Ilọrin ni abẹwo ọhun ti waye, ti a si gbọ pe Ajihinrere Stephen Awoyale, to jẹ olori wọn lo lewaju igbimọ to lọ ṣabẹwo si gomina.
 
Nibẹ ni gomina ti lewaju lati dide iṣẹju kan ni iranti amugbalẹgbẹ rẹ pataki lori ọrọ ẹsin, eyi to jade laye laipẹ yii, Samuel Adedayọ, ati alaga ẹgbẹ awọn Kristẹẹni, nipinlẹ naa, Most Reverend Paul Ọlawoore.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI