Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq tun ti fi ọrọ idaniloju sita lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii wi pe awọn ti ṣetan lati maa ṣe iranlọwọ to ba yẹ lasiko fun gbogbo ileeṣẹ eleto aabo to wa nipinlẹ ọhun.
O ni oun yoo rii daju pe ajọṣepọ to dan mọran n wa laaarin ijọba ati gbogbo ileeṣẹ eleto aabo, paapaa awọn ologun nipinlẹ Kwara.
Nibi akanṣe eto Nigerian Army/West Africa Social Activities (WASA), eyi ti 22 Armoured Brigade to wa ni Ṣobi pẹlu ajọṣepọ Army Institute of Science and Education Technology ni Ṣobi, ilu Ilọrin ṣagbatẹru rẹ ni Gomina AbdulRazaq ti sọrọ yii jade.
Nigba to n ṣe koriya fawọn ọga ologun ati gbogbo ileeṣẹ eleto aabọ nibi akanṣe eto ọhun, ti ọdun 2021, o sọ pe iṣẹ takuntakun ni wọn n ṣe, paapaa lakooko ti orileede Naijiria n koju ipenija lori eto aabo.
AbdulRazaq jẹ ko di mimọ pe kii ṣe tẹnu, ipinlẹ naa wa lara awọn ipinlẹ to n jẹ anfaani eto aabo to peye kọja sisọ.
Siwaju sii lo jẹ ko di mimọ pe gbogbo igba atawọn ileeṣẹ eleto aabo ba ti n beere fun iranwọ, lawọn yoo maa dide lati ṣe e lai fi ẹlẹyamẹya ṣe.
No comments:
Post a Comment