Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti sọ pe ki ẹnikẹni ma ṣe gba awọn iroyin ayederu to n tabuku ba ọrọ ẹsin, paapaa lori ọrọ ijaabu gbọ, nitori pe awọn ko ṣe ojusaaju lori ọrọ ijaabu naa, paapaa ẹsin.
AbdulRazaq ninu atẹjade to gbe jade lana lo ti sọ pe oriṣiriṣi ayederu iroyin ati apilẹkọ lawọn akọroyin alatẹnujẹ ti gbe jade, lati fi ṣi awọn eeyan lọkan, eyi to sọ pe ko bojumu to.
O ni pupọ awọn apilẹkọ ati iroyin ti wọn ti gbe jade ni kii ṣe otitọ, ati pe oun yoo ṣalaye ipo wọn lori ọrọ ijaabu yii.
"Lori idajọ ile-ẹjọ, eyi to fidi mulẹ nipa iwe ofin, ofin ijọba apapọ ati ipinlẹ, ati lati bọwọ fun erongba awọn eeyan, lilo ijaabu lawọn ile-ẹkọ jẹ ohun to ba ofin mu, ti awọn si gbọdọ daabobo ẹtọ awọn eeyan, paapaa awọn to ba wu lati lo o."
No comments:
Post a Comment