Wọ́n ju akẹ́kọ̀ọ́ Mapoly sẹ́wọ̀n oṣù méje n'Íbàdàn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, February 13, 2022

Wọ́n ju akẹ́kọ̀ọ́ Mapoly sẹ́wọ̀n oṣù méje n'Íbàdàn


Ile-ẹjọ giga apapọ to wa nilu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ ti ju gendekunrin, ọmọ ọdun mẹrinlelogun kan, Adebọwale Babatunde Ismail sẹwọn oṣu meje gbako pẹlu iṣẹ aṣekara lori ẹsun iwa jibiti to n lu lori ayelujara, eyi ti wọn n pe ni 'Yahoo-Yahoo'.
 
Akẹkọọ ile-ẹkọ gbogboniṣe ti Moshood Abiọla to wa nilu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun ni wọn pe Ismail, ẹka ikẹkọọ imọ kọmuputa ni wọn tun pe e, ti wọn si ni ogbologbo ni ninu ka lu jibiti ori ayelujara.
 
Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Onidajọ Uche Agomoh sọ pe awọon ẹri to tako Ismail niwaju oun kọja ohun ti wọn le maa pe ni irọ, ati paapaa boun funra rẹ tun ti ṣe jẹwọ wi pe lotitọ ni ẹsun ti wọn fi kan oun.
 
Wọn ni orukọ kan, Annabel Torrens ni Ismail n lo lori ayelujara lati maa fi lu awọn eeyan ni jibiti, to si fi gba owo lọwọ ẹnikan ti wọn pe ni John Dauherty nipasẹ imeeli kan to jẹ [email protected].

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI