Ìdí pàtàkì tí wọ́n ṣe fi Sunday Ìgbòho sílẹ̀ gan-an rèé - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 7, 2022

Ìdí pàtàkì tí wọ́n ṣe fi Sunday Ìgbòho sílẹ̀ gan-an rèé


Kii ṣe iroyin tuntun mọ Oloye Adeyemo Sunday Igboho ti gba ìtúsílẹ̀ kuro lọgba ẹwọn ní orile-ede Benin.

Wọn tu Igboho silẹ lọjọ Aje, Mọnde oni nilu Cotonou.

Awọn alaṣẹ orilẹede Benin fa Igboho le olori ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua, Ọjọgbọn Banji Akinloye ati Ọjọgbọn Wale Adeniran lọwọ.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, agbẹjọro agba Yomi Aliyu to jẹ agbẹjọro fun Oloye Sunday Adeyẹmọ, o sọrọ lori idi ti won ṣe tu Igboho Òòṣà silẹ bayii.

Aliyu ni pe wọn ti fa Sunday Igboho le awọn Dọkita  lọ́wọ́ ni ni Benin lati gba itọju to peye.

O ni pe Igboho Ooṣa ni wọ́n fa le Ọjọgbọn Banji Akintoye to jẹ alaga ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua lọwọ.

Wọ́n ni pe Sunday Igboho ko gbọ́dọ́ kuro ni orileede Benin bayii.

Wọ́n ni Ooṣa ni oore ọ̀fẹ́ lati lọ́ ṣe itoju ara re nibi ti ọ̀rọ̀ de duro yii.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI