Judith, oṣiṣẹ banki to lu jibiti ti foju ba ile-ẹjọ o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, March 17, 2022

Judith, oṣiṣẹ banki to lu jibiti ti foju ba ile-ẹjọ o


Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede yii, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC) ti f'oju oṣiṣẹ banki kan, Judith Nneka Nwagwu ba ile-ẹjọ lori ẹsun jibiti.

Iwaju Onidajọ D. A. Onyefulu ti ile ẹjọ giga t'ipinlẹ Anambra to wa niluu Onitsha ni Judith ti kawọ pọyin rojọ, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Ẹsun meje ọtọọtọ to nii ṣe pẹlu iwa jibiti, yiyi iwe ati gbigba owo lọna ti ko tọ la gbọ pe wọn fi kan Judith. Owo ti wọn lo ji ko la gbọ pe o din diẹ ni idaji biliọnu kan naira N452,047,000
 
Yatọ si eyi, a gbọ pe Judith tun fọgbọn gba owo to din diẹ ni ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrun lọna igba naira, N192,000,000 lọwọ onibara ile ifowopamọ to ti n ṣiṣẹ, ẹni ti wọn loun lo n ba a mojuto akanti rẹ.

Wọn ni ẹtanjẹ wi pe banki naa fẹẹ ta ẹgbẹrun lọna irinwo owo dọla, iyẹn $400,000 ni iṣiro N480.

Onidajọ Onyefulu wa ni ki wọn gba beeli obinrin naa pẹlu miliọnu mẹwaa naira ati oniduro kan ti ilẹ rẹ ko jinna si ayika kọọtu naa.
 
Bẹẹ lo sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kọkanla, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu karun-un, ati ọjọ kẹjọ, ọsu kẹfa, ọdun yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI