O ma ṣe o! AbdulRazaq ba Musa Yeketi kẹdun iku ọmọ rẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, March 23, 2022

O ma ṣe o! AbdulRazaq ba Musa Yeketi kẹdun iku ọmọ rẹ


Gomina ipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq ti ba kọmiṣanna tẹlẹri fun ọrọ eto ẹkọ nipinlẹ naa, Onimọ-ẹrọ Musa Yeketi kẹdun iku ọmọ rẹ, Onimọ-ẹrọ Nafiu, ẹni to jade laye laipẹ yii.
 
Yeketi, ẹni to tun jẹ ọkan pataki lara awọn agba lẹgbẹ oṣelu APC la gbọ pe o padanu ọmọ rẹ yii lẹyin aisan rampẹ.
 
Ninu atẹjade ti gomina gbe jade lalẹ ana, ti i ṣe Tuside lo ti ṣapejuwe iku naa gẹgẹ bi ajalu ati eyi to ba ni lọkan jẹ gidigidi, to si n gba agba oṣelu naa lamọran lati mu ọkan le.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI