Oludije sipo gomina nipinlẹ Ogun gbe igba baara lati gba fọọmu PDP - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, March 21, 2022

Oludije sipo gomina nipinlẹ Ogun gbe igba baara lati gba fọọmu PDP


Ọkan lara awọn to n foju sọna lati dije du ipo gomina nipinlẹ Ogun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP nipinlẹ Ogun, Ọmọọba John Adegbọla ti bẹrẹ sii beere fun iranlọwọ awọn ẹlẹyinju aanu kaakiri ipinlẹ naa, paapaa lagbaye lati ṣagbatẹru ipinnu rẹ.

AWIKONKO gbọ pe ọkunrin naa jade du ipo gomina ipinlẹ Ogun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Advanced Alliance Party, AAP ninu idibo ọdun 2019, ṣugbọn to padanu.

Ni bayii, a gbọ pe Ọmọọba Adegbọla ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP lati jade du ipo nibẹ, ti wọn si ni gbogbo ọna lo n wa bayii, lati lẹ ri fọọmu lati du ipo naa gba.

Gẹgẹ bi ọkan lara awọn fọto ti ọkunrin naa fi soju opo ayelujara ti fesibuuku rẹ laipẹ yii, eyi to tẹ AWIKONKO lọwọ lo ti jẹ ko di mimọ pe owo nla loun nilo lati gba fọọmu toun yoo fi du ipo gomina labẹ ẹgbẹ PDP.
 
Miliọnu mọkanlelogun la gbọ pe Ọmọọba Adegbọla n wa lati fi gba fọọmu ti yoo fi jade du ipo gomina lọdun 2023 to n bọ lọna yii, ti a si gbọ pe o gbọdọ ri owo naa ko too to ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹrin, ọdun 2022 ti a wa yii. 

Ṣugbọn ṣa, lara awọn to ba AWIKONKO sọrọ jẹ ko ye wa pe awọn ọrẹ ati ololufẹ to nigbagbọ ninu ohun ti ọkunrin naa ni ipinnu fun ipinlẹ Ogun ni wọn dide lati beere fun iranlọwọ owo, nitori ti wọn sọ pe ipinnu rere lo ni fun idagbasoke ipinlẹ ọhun.
 

 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI