Wọn ju Amechi sẹwọn ọdun kan ati ọjọ kan l'Amẹrika lori ẹsun gbajuẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, March 8, 2022

Wọn ju Amechi sẹwọn ọdun kan ati ọjọ kan l'Amẹrika lori ẹsun gbajuẹ


Ọmọ orileede Naijiria kan to fi ilẹ Amẹrika ṣe ibugbe, Augustine Amechi, ọmọ ọdun mẹrinlelogun lo ti ri ẹwọn ọdun kan ati ọjọ he nitori ẹsun jibiti ti wọn fi kan an.
 
Owo to din diẹ ni igba miliọnu naira, N165m, iyẹn ẹgbẹrun lọna irinwo dọla din diẹ, $398,601.92 la gbọ pe Amechi jigbe salọ, ṣugbọn ti ọwọ pada tẹ ẹ.
 
AWIKONKO gbọ pe Onidajọ ile-ẹjọ United States District Judge, Robert C. Chambers lo paṣẹ pe ki Amechi lọ fi ẹwọn naa gbara, pẹlu iṣẹ aṣekara.
 
Lara awọon to ṣe iwadii finnifinni lori ẹsun ti wọn fi kan Amechi yii ni US Secret Service, Postal Inspection Service, atawọn ileeṣẹ miran.
 
Agbegbe kan ti wọn pe ni Huntington, West Virginia, USA ni Amechi n gbe, to si tun n lọ fasiti Marshall, gẹgẹ bi iwe ile-ẹjọ ṣe fi han. Inu oṣu kọkanla, ọdun to kọja ni Amechi gba wi pe oun jbẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI