Orin igba ọtun lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP nipinlẹ Kwara n kọ nigba ti ẹgbẹẹgbẹrun wọn fẹgbẹ silẹ, ti wọn si ya lọ sinu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC lati darapọ mọ wọn nibẹ.
Ẹgbẹẹgbẹrun awọn eeyan naa lati agbegbe Lakanla to wa nijọba ibilẹ Ifẹlodun, ipinlẹ Kwara la gbọ pe wọn lawọn ko le tẹsiwaju lati maa ṣe ẹgbẹ alatako mọ, bi ko ṣe pe kawọn kọju sibi ti aye kọju si.
Nigba to n lewaju awọn eeyan naa, Alagba Joseph Adediran, ẹni to jẹ akọwe ipolongo lẹgbẹ oṣelu PDP sọ pe awọn iwa ati idari Gomina AbdulRazaq lo wu awọn lori, tawọn fi wo o pe ẹni to ṣee tẹle ni.
Alagba Adediran sọ pe bo tilẹ jẹ pe ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP tọkantọkan lawọn jẹ, ṣugbọn to jẹ pe awọn idagbasoke to yẹ ki wọn maa jẹ anfaani rẹ lagbegbe wọn ni wọn ko ri, ti awọn ko si tun ri ẹtọ awọn gba gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ.
Siwaju sii lo jẹ ko di mimọ pe awọn akanṣe iṣẹ ti Gomina n ṣe lai fi ti ẹlẹyamẹya ṣe lo jẹ kawọno naa ronu lati darapọ mọ ọn, ki wọn le tubọ jọ gbe ipinlẹ naa larugẹ de ibi to yẹ ko de.
Bakan naa lo dupẹ lọwọ aṣoju-ṣofin to n ṣoju ẹkun Oke-Ode, Ọnarebu Owolabi, to si sọ pe ọna to ba tọ lawọn naa yoo tọ.
Nigba toun naa n gba ẹnu gbogbo awọn obinrin to ṣẹṣẹ darapọ mọ ẹgbẹ yii sọrọ, Alaaja Iyabọ Aliyu sọ pe o ti pẹ tawọn ko i ri anfaani kankan jẹ lẹgbẹ APC, to si lawọn ti ṣetan bayii lati fi gbogbo ọkan wọn tẹlẹ APC fun ilọsiwaju ati idagbasoke ti 'Gomina Mẹkunnu' n ṣe.
No comments:
Post a Comment