Wọn ti bura fawọn oloye ẹgbẹ oṣelu APC tuntun nipinlẹ Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, March 17, 2022

Wọn ti bura fawọn oloye ẹgbẹ oṣelu APC tuntun nipinlẹ Kwara


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq, tipinlẹ Kwara, l'Ọjọru, Wẹside ana ti bura fun gbogbo awọn oloye tuntun ti yoo tukọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) nipinlẹ naa, to si gba wọn lamọran lati ma ṣe ṣoju saaju lẹnu iṣẹ wọn.
 
Nibi ibura naa ni Gomina AbdulRazaq ti sọ ọ nita gbangba wi pe ko tii si ẹgbẹ oṣelu naa, tabi ijọba naa to ṣi mu ileri wọn ṣe lakoko ipolongo idibo bii toun.
 
O ni lẹka eto ẹkọ, ilera, nina owo ijọba, aisi ẹlẹyamẹya ninu eto iṣejọba ati ṣiṣẹ iranwọ fawọn ọdọ, eyi toun ṣe ileri wọn loun ti mu ṣẹ patapata.
 
Bakan naa lo sọ pe awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Kwara ti sọ pe awọn ko tun le gbe ijọba fawọn ọjẹlu, ijẹn ikooko ajegunjẹran ati isọngbe wọn mọ lati maa ṣakoso.
 
Gbogbo awọn agbaagba, alẹnulọrọ ninu ẹgbẹ oṣelu APC kaakiri ipinlẹ naa la gbọ pe wọn wa nibi ibura yii, nibi ti ẹsẹ ko ti gbero rara, ti awọn araalu si wa fi idunnu wọn han si gomina wọn.
 


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI