Lẹyin ọdun marundinlọgbọn, Tẹlifiṣan Kwara bẹrẹ iṣẹ wakati mẹrinlelogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, April 4, 2022

Lẹyin ọdun marundinlọgbọn, Tẹlifiṣan Kwara bẹrẹ iṣẹ wakati mẹrinlelogun


Lonii, ọjọ Aje, Mọnde ni itan tuntun yoo tun balẹ nipinlẹ Kwara, pẹlu bi ileeṣẹ amohunmaworan ipinlẹ naa ṣe bẹrẹ iṣẹ aṣeyipo oni wakati mẹrinlelogun lai dawọ duro.

Ọdun karundinlọgbọn ree ti wọn ti da ileeṣẹ amohunmaworan naa silẹ, to si jẹ pe wakati mẹtadinlogun ni wọn fi n ṣiṣẹ wọn.

Nigba to n bawọn akọroyin sọrọ niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, Kọmiṣanna fun Ọrọ eto ibaraẹnisọrọ, Ọgbẹni Ọlabọde Towoju sọ pe awọn eto ibilẹ loriṣiriṣi ni wọn yoo maa gbe larigẹ to pọ ju. 

O sọ pe awọn eto ibilẹ naa yoomaa mu igbega ati ilọsiwaju ba aṣa, iṣe ati ede abinibi ipinlẹ Kwara.

Siwaju sii lo sọ pe inu awọn eeyan dun nigba ti tẹlifiṣan ipinlẹ naa bẹrẹ iṣẹ wakati mẹrinlelogun lọjọ kin-ni-in, oṣu keji, ọdun yii, lẹyin ti wọn yan ogbontarigi akọṣẹmọṣẹ gẹgẹ bi alakoso agba.

Bakan naa lo sọ pe eyi ko ṣee ṣe tẹle nigba ti ijọba ko fi bẹẹ kọbi ara sii, ṣugbọn kete ti ọrọ ileeṣẹ naa ti jẹ gomina wọn logun, ni itẹsiwaju ti de.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI