Mi o mọ nnkankan nipa iku awọn Ọba alaye l'Ọyọọ - Gomina Makinde pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, April 25, 2022

Mi o mọ nnkankan nipa iku awọn Ọba alaye l'Ọyọọ - Gomina Makinde pariwo sita


Gomina Ṣeyi Makinde ti ipinlẹ Ọyọ ti pariwo sita wi pe oun ko mọ nnkankan nipa bi awọn ọba alaye ṣe n papoda nipinlẹ Ọyọ, ati pe eto Ọlọrun ni.
 
Bẹ o ba gbagbe, lati bi ọjọ meloo sẹyin, iyẹn lẹyin iroyin iku Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi kẹta jade sita l'awọn eeyan ti bẹrẹ sii gbe oriṣiriṣi ọrọ jade wi pe Gomina Ṣeyi Makinde nikan ni gomina ti yoo sin Ọba alaye mẹta ọtọọtọ, eyi ti ko ṣẹlẹri ninu itan ipinlẹ Ọyọ, ati pe yoo ni ohun to n fi iku awọn ọba naa ṣe.
 
Ọdun to kọja ni Ṣọun tilu Ogbomọṣọ waja, oṣu kin-in-ni ọdun yii ni Olubadan naa papoda, ko to tun di pe Alaafin Ọyọ naa tẹrigbaṣọ.
 
Ana, ọjọ Aiku, Sannde ni Gomina Makinde sọrọ naa jade lakoko to n ba awọn mọlẹbi kabiyesi ati gbogbo Ọyọmesi kẹdun iku Ọba Adeyẹmi.
 
Nibẹ lo ti ṣeleri wi pe oun yoo sa gbogbo ipa ati akitiyan oun lati ri i pe eto isinku to bu iyu kun oloogbe waye.
 
Bakan naa lo gba gbogbo Ọyọmesi lamọran lati dide giri, ki wọn si ma ṣe ojusaaju nipa yiyan Alaafin tuntun sipo, ati pe ijọba oun yoo ri daju pe erongba Kabiyesi to papoda wa si imuṣẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI