Lẹyin ọjọ kẹta, wọn tun pasitọ ijọ Aguda ati ọmọ rẹ silẹ lahamọ ajinigbe - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, May 25, 2022

Lẹyin ọjọ kẹta, wọn tun pasitọ ijọ Aguda ati ọmọ rẹ silẹ lahamọ ajinigbe


Orin ọpẹ lo gba ẹnu awọn mọlẹbi, ọrẹ ati afẹnifẹre gbajumọ ojiṣẹ Ọlọrun ijọ Aguda, iyẹn Anglican kan n'ipinlẹ Ondo, Olu Ọbanla ati ọmọ rẹ, lori b'awọn ajinigbe ṣe tu wọn silẹ.
 
Bẹ o ba gbagbe, ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja yii ni iroyin naa jade sita wi pe awọn ajinigbe ti ji Olu Ọbanla ati ọmọ rẹ gbe, ti awọn ajinigbe naa si n beere owo ti ko din ni miliọnu mẹwaa naira.

Ibi irin-ajo kan la gbọ pe wọn ti n bọ, ko to di pe awọn ajinigbe naa dena de wọn, loju ọna Ifọn-Okeluse, ijọba ibile Ose, ipinlẹ Ondo, ti wọn si ko wọn salọ.
 
Nigba to n f'idi rẹ mulẹ pe lotitọ ni wọn ti gba ominira, agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa, Funmilayọ Ọdunlami sọ pe nnkan bi agogo mejila aabọ ọjọ Aje, Mọnde ni wọn tu wọn silẹ.

AWIKONKO gbọ pe miliọnu kan naira l'awọn mọlẹbi lawọn le ri ko kale, ṣugbọn ti awọn ajinigbe ọhun sọ pe awọn ko le gba a.
 
Ju gbogbo rẹ lọ, a ko ti i gbọ boya awọn eeyan naa pada gba owo naa, tabi wọn ko gba owo ko to di pe wọn tu wọn silẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI