Àwọn òṣìṣẹ́ lẹ́tọ̀ọ́ láti bèèrè fún ẹ̀tọ́ wọn - Adérìnókùn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, June 28, 2022

Àwọn òṣìṣẹ́ lẹ́tọ̀ọ́ láti bèèrè fún ẹ̀tọ́ wọn - Adérìnókùn


Oludije s'ipo ile igbimọ aṣofin agba lorileede Naijiria, l'ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun, labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Oloye Olumide Aderinokun ti sọ pe awọn oṣiṣẹ lẹtọọ labẹ ofin lati beere ẹtọ wọn lọwọ ijọba.
 
Aderinokun lo sọrọ naa lati fi bi bu ẹnu atẹ lu iṣakoso Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun lori b'awọn oṣiṣẹ kaakiri ipinlẹ naa ṣe bẹrẹ iyanṣẹlodi ọlọjọ gbọgbọrọ lonii, ọjọ Iṣẹgun ti i ṣe Tusidee.
 
Ninu atẹjade to fi ranṣẹ si wa lati ọwọ akọwe iroyin rẹ, Taye Taiwo lonii, o sọ pe ṣe lo yẹ ki gomina naa mu ọrọ awọn oṣiṣẹ lokunkundun, nitori pe wọn n gbiyanju pupọ fun ijọba, ko si yẹ ki wọn maa fi ẹtọ wọn dun wọn.

O ni kaka ki ijọba jẹ ki awọn oṣiṣẹ maa gbadun owo ọya wọn, ṣe ni wọn n fi iya jẹ wọn nipa yiyọ owo wọn Reacting to the workers' resolution to embark on an indefinite strike from Tuesday, Chief Aderinokun believes the government is niyọkuyọ, eyi ti ko yẹ ko ri bẹẹ.
 
Bẹ o ba gbagbe, lọjọ Aje, Mọnde ana l'awọn oṣiṣẹ labẹ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ bi i National Labour Congress (NLC), Trade Union Congress (TUC) ati Joint Negotiating Committee (JNC) kede iyanṣẹlodi ọlọjọ gbọgbọrọ, iyẹn titi di igba ti Gomina Abiọdun yoo fi ṣe ohun ti wọn n fẹ fun wọn.
 
Lara awọn ti iyanṣẹlodi naa kan ni ile-ẹkọ ijọba lapapọ, oṣibitu ijọba ipinlẹ patapata, gbogbo ẹka ileeṣẹ ijọba patapata at'awọn mi in ti wọn wa labẹ ijọba ipinlẹ Ogun.
 
Nigba to n kọminu lori iyanṣẹlodi ọhun, Akinruyiwa t'ilu Owu sọ pe ṣe lo yẹ ki gomina ranti iwe adehun to tọwọ bọ pẹlu awọn ẹgbẹ yii l'ọdun 2020, ko si gbe igbesẹ gidi lori rẹ.
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI