Gomina Akeredolu ati iyawo ẹ bu s'ẹkun nita gbangba - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 18, 2022

Gomina Akeredolu ati iyawo ẹ bu s'ẹkun nita gbangba


Gomina Oluwarotimi Akeredolu ti ipinlẹ Ondo ati iyawo rẹ, Arabinrin Betty Anyanwu Akeredolu ti bu sẹkun ninu ijọ Saint Francis Catholic Church, to wa ladugbo Ọwaluwa, niluu Ọwọ, iyẹn nibi ti awọn agbebọn kan ti wa ṣe ikọlu s'awọn ọmọ ijọ naa lọjọ isinmi to kọja lọhun.
 
Nibẹ lo ti tẹnu mọ ọn wi pe oun ti kuna awọn eeyan oun latari aile daabo bo awọn to fi ibo gbe oun wọle ninu eto idibo to kọja lọ.
 
Ọjọ Ẹti ti i ṣe Furaide to kọja yii ni wọn ṣe isin ikẹyin fun awọn mejilelogun ninu ogoji awọn ti wọn kagbako iku nibi ikọlu ọhun.
 
Gomina Rotimi Akeredolu, wa ṣe ileri wi pe oun yoo sa ipa oun debi wi pe iru nnkan bẹẹ ko tun ni i ṣẹlẹ mọ, nitori pe oun gba pe ọta pọ fun wọn, ṣugbọn awọn yoo bori gbogbo wọn.
 
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe 
“A ti kuna lati daabo bo awọn eeyan wọnyi. Ki i ṣe nitori pe a ko gbiyanju, ṣugbọn bi ko ṣe nitori pe awọn alagbara buburu ti wọn wa ni odi keji lagbara, wọn si ni igi lẹyin ọgba. Wọn ko le maa j'ọba lọ lori wa lọ titi.
 
“N'igba ti mo ri awọn ori to sun lọ nibi, o tunmọ si ọpọ nnkan. Ohun to ṣẹlẹ si wa n'ipinlẹ Ondo kọja afẹnusọ. Ọpọ ọrọ la le fi ṣe apejuwe rẹ: iwa buburu, ọdaju. Ṣugbọn mo ni igbagbọ wi pe a ṣ maa ri awọn ọrọ ti a le fi ṣapejuwe rẹ, ṣugbọn lasiko yii, mi o ti i mọ ohun ti mo le sọ.

“Awọn oku mejilelogun lo wa ninu gbọngan yii. Diẹ ninu wọn ni wọn ti sinku wọn nitori pe awọn eeyan wọn ko le duro de iru ọjọ oni. Ṣugbọn nigba ti a ka gbẹyin, awọn ẹranko buburu yii wa sinu ijọ, wọn si pa ogoji eeyan nipakupa.”
 
Nigba toun naa n sọrọ, olori ijọ naa, Biṣọọbu ijọ Ondo Catholic Diocese, Ọmọwe Jude Arogundade, sọ pe Gomina Akeredolu ko kuna nipa didaabo bo awọn eeyan rẹ.
 
“Ẹ ko kuna, akikanju ologun lẹ jẹ. Ipinnu ati itara yin lati daabo bo gbogbo awọn to dibo yan yin ko ṣee sọ. Ẹ ti gbiyanju agbara yin.
 

 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI