Gbajumọ oloṣelu Naijiria l'awọn eleyii lu ni jibiti miliọnu mẹrinlelogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 27, 2022

Gbajumọ oloṣelu Naijiria l'awọn eleyii lu ni jibiti miliọnu mẹrinlelogun


Ọjọ́ gbogbo ní ti olè, àmọ́ ọjọ́ kan ṣoṣo pere ni ti olohun. Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu afurasi Alfa àti Babalawo kan nigba ti ọwọ ajọ EFCC tẹ wọn lórí ẹsun pe wọn lu oloselu kan ni jìbìtì.

Orúkọ awọn afurasi mejeeji naa ni Alfa Abiodun Ibrahim ati Wale Adifala

Àwọn afurasi naa si ni wọn fẹ́sun kan pe wọn gba Oludije sipo ile asoju-sofin kan ni ìpínlẹ̀ Ekiti.

Iroyin kan tí àjọ EFCC fisita loju opo Instagram rẹ lo sisọ loju iṣẹlẹ naa fun araye.

Atejade naa ni owo to le díẹ̀ ni mílíọ̀nù lọ́nà mẹ́rinlelogun naira sì (N24, 071,000) ni EFCC fẹsun kan pe wọn gba lọwọ oloselu náà.

Owo naa si ni awọn afurasi oníjìbìtì naa ni awọn yoo lo lati fi ba oloselu naa wa agbara lori ipo to n du.

Awọn afurasi mejeeji naa si lo jẹwọ pe lootọ ni awọn ẹsun ti wọn fi kan awọn naa.

Nigba to n ka boroboro fun EFCC, Babalawo Adifala ni lootọ ni òun gba owo lọwọ oloselu naa.

O ni lara owo tòun gba ni N2. 9m eyi ti oun lo lati ra eroja fun etutu bíi maalu dúdú, aláwọ̀ esuru àti funfun.

Bakan naa lo ni oun tun ra ọpọlọpọ agbo, turari, òrùka àti bẹẹ bẹẹ lọ.

“Kódà, mo tun kan si Ifawole Ajibola lori ọrọ yii, ta si dijọ ṣe etutu naa papọ, titi tí àwọn EFCC fi wa mu wa”

Alfa Ibrahim, to ni oun ni oun kọkọ mọ oloselu ti wọn lu ni jibiti salaye pe lootọ ni oun gba owo lọwọ rẹ̀ ni àìmọye igba.

“Iṣẹ́ tiwa ní pe ka ṣe adura ati awọn etutu to ṣe koko, eyi ta ṣe, ta si fi iyoku si ọwọ Ọlọrun.

Amọ nigba to ya, wọn gbe ijoko ile asoju-sofin kuro ni ilu Oye (Ekiti, lọ si Ikole-Ekiti"
 
Lati BBC YORUBA

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI