Ibo 2023: Afi ti wọn ba yi ibo nikan ni Tinubu le di Aarẹ Naijiria - Wolii Ayọdele ju bọmbu asọtẹlẹ sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, July 9, 2022

Ibo 2023: Afi ti wọn ba yi ibo nikan ni Tinubu le di Aarẹ Naijiria - Wolii Ayọdele ju bọmbu asọtẹlẹ sita


Alaṣẹ ati oludasilẹ ṣọọṣi INRI Evangelical Spiritual to wa niluu Eko, Wolii Elijah Babatunde Ayọdele ti sọ pe oludije sipo aarẹ orileede Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Bọla Ahmẹd Tinubu ko nibi kankan to n lọ.
 
Wolii Ayọdele sọ pe ayafi bi ẹgbẹ oṣelu APC ba yi ibo fun Tinubu nikan lo le fi jawe olubori, bi bẹẹ kọ, niṣe lo kan n tan ara rẹ jẹ lasan.
 
Wolii Ayọdele lo ju bọmbu asọtẹlẹ yii sita lonii, ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹsan, oṣu keje, nibi eto ikojade iwe asọtẹlẹ ọlọdọọdun rẹ to pe ni 'Warnings To The Nations', to waye ninu ijọ naa.
 
Nibẹ lo tun ti sọ pe asiko naa ree f'awọn ẹya Igbo lati de ipo aarẹ, ati pe bi wọn ba fi le kuna lati de ipo aarẹ l'ọdun 2023, iya nla ni yoo jẹ awọn iran wọn to n bọ lẹyin.

O ni ko si eyikeyi ninu awọn to jade lati du ipo aarẹ l'abẹ asia awọn ẹgbẹ oṣelu to gbajumọ daadaa bayii ti wọn l'awọn nnkan amuyẹ to le jẹ ki wọn wa ọkọ orileede Naijiria de ebute ogo lẹyin idibo ọdun 2023.

Wolii Ayọdele to sọ pe oun naa wa lẹyin wi pe ki Yoruba gba iṣakoso orileede Naijiria, sọ pe o ṣeni laanu wi pe asiko yii ki i ṣe fun ẹya Yoruba, bi ko ṣe ti awọn Igbo lati di aarẹ.
 
O loun ko ri Tinubu gẹgẹ bi ẹni le jawe olubori ninu eto idibo to n bọ lọna yii, ayafi bi ẹgbẹ APC ba yi ibo naa.

“Ọna kan ṣoṣo ti Tinubu le fi bori ni ki wọn yi ibo. Mi o korira rẹ (Tinubu), mo kan n sọrọ gẹgẹ bi Wolii Ọlọrun ni. Mi o korira rẹ, mi o si ni erongba buruku si i, ṣugbọn bi Tinubu ba di aarẹ orileede yii, iṣakoso rẹ maa buru ju ti Buhari lọ
 
“Naijiria ko ni i kuro loju kan ṣoṣo, yoo si jẹ orileede to kuna,ti yoo si maa gba itiju kaakiri. Naijiria ko ni kuro loju kan lasiko Tinubu. Ajalu ni Tinubu yoo jẹ fun Naijiria. Mi o korira rẹ, mo si wa lẹyin ẹya Yoruba lati gbajọba, ṣugbọn ki i ṣe asiko Yoruba la wa yii, bi ko ṣe ti ẹya Igbo. Bi Igbo ba si padanu ipo naa lakoko yii, iran wọn to n bọ yoo jẹ ninu iya naa.”
 
Bakan naa lo tun jé ko di mimọ pe awọn ti Tinubu gbojule yoo dalẹ rẹ, ati pe Alaaji Atiku Abubakar yoo gbiyanju gidi lati di aarẹ, ṣugbọn ko ni ṣee ṣe fun un.
 
Bẹẹ lo sọ pe agba ofifo lasan ni Peter Obi jẹ pẹlu ariwo to n pa kaakiri.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI