Ikunlẹ abiyamọ o! Ọja Bodija n'Ibadan jona gburugburu, ọpọ dukia olowo iyebiye lo parun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, July 12, 2022

Ikunlẹ abiyamọ o! Ọja Bodija n'Ibadan jona gburugburu, ọpọ dukia olowo iyebiye lo parun


Ṣe ni ariwo ikunlẹ abiyamọ sọ ninu gbajugbaja ọja agbaye nni, to wa niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, iyẹn Ọja Bodija, n'igba ti ina deedee ṣẹyọ lojiji, to si fi ọpọ dukia olowo iyebiye ṣofo danu.
 
Apa kan ninu ọja ọhun la gbọ pe o jọna di eeru laarọ kutu ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, iyẹn lakoko t'awọn eeyan fẹẹ bẹrẹ si i ta ọja wọn lẹyin ayẹyẹ pọpọṣinṣin ọdun Ileya to kọja.
 
Pupọ awọn ti ṣọọbu wọn fara gba ninu ijamba ina yii, ni wọn bu sẹkun, ti wọn si n sọ pe ọja to le ni ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu owo naira l'awọn padanu.
 
A gbọ pe kani ki i ṣe pe awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ panapana tete debẹ ni, boya ni ko ni jẹ pe gbogbo ọja ọhun ni yoo jona tan patapata, ṣugbọn nipa iranlọwọ wọn, wọn tete dẹkun rẹ.
 

Bo tilẹ pe titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii la ko ti i ri alakoso ileeṣẹ panapana n'ipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Ismail Adeleke sọrọ, sibẹ a ko ti i gbọ nipa ohun to ṣokunfa ijamba ina ọhun.
 
Ọja Bodija yii lo wa n'ijọba ibilẹ idagbasoke ti Aarẹ Latoṣa, ijọba ibilẹ Ariwa Ibadan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI