Ìmọ́tótó wọ Kwara, wọ́n lé gbogbo àwọn tó n tọrọ báárà danù - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, July 9, 2022

Ìmọ́tótó wọ Kwara, wọ́n lé gbogbo àwọn tó n tọrọ báárà danù


Bi ipalẹmọ ayẹyẹ ọdun Ileya ṣe ti sunmọ etile, ijọba ipinlẹ Kwara labẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti palẹmọ gbogbo awọn to n tọrọ baara kaakiri ipinlẹ naa danu, lai fi oju aano wo eyikeyi ninu wọn.

Ijọba Kwara tun ti paṣẹ pe ohun ko fẹẹ ri ẹnikẹni to n tọrọ baara mọ layika ati agbegbe ilu Ilọrin to jẹ olu ilu ipinlẹ Kwara.

Kọmiṣanna f'ọrọ eto idagbasoke afẹ, Ọnarebu Abọsẹde Arẹmu lo lewaju ikọ to lọ le awọn to n tọrọ baara naa danu, to si ni ki onikaluku wọn gba ipinlẹ ti wọn ti wa lọ.

Awọn agbegbe bi i Challenge, Gerin Alimi, garaaji Ọffa, Post Office, Unity Road, ati layipo Jẹnẹra ni iroyin fi to wa leti pe wọn ti le gbogbo awọn to n tọrọ baara naa kuro.

Aarọ kutu la gbọ pe awọn aṣoju ijọba lẹka eto ayika ti jade lati le gbogbo wọn danu, paapaa bi wọn ṣe sọ pe wọn n ko idọti ba ipinlẹ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI