Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Oluwarotimi Akeredolu ti paṣẹ pe ki olori awọn oṣiṣẹ ipinlẹ naa le gbogbo awọn oṣiṣẹ ti aṣiri wọn ba tu wi pe wọn n gba owo oṣu lọna meji tabi ju bẹẹ lọ.
Akeredolu lo pa aṣẹ yii lẹyin ti aṣiri kan tu sita wi pe ọpọ awọn oṣiṣẹ ijọba ni wọn n gba owo oṣu to ju ẹyọkan ṣoṣo lọ, eyi to ni ko bojumu to, ati pe iwa jibiti gba a ni.
Nigba to n paṣẹ naa fun olori awọn oṣiṣẹ, Pasitọ John Adeyẹmọ nibi to ti n ba igbimọ to ṣakoso agbeyẹwo sisan kwo oṣu fawọn oṣiṣẹ, Akeredolu ni gbogbo awọn to n gba owo oṣu ti ko tọ si wọn lo n pa ijọba lars, ati pe wọn ko yẹ lati ṣiṣẹ ilu.
Laipẹ yii ni Gomina Akeredolu gbe igbimọ ẹlẹni meje dide lati ṣe agbeyẹwo bi owo oṣu ṣe n jade s'apo awọn oṣiṣẹ ijọba ati awọn oṣiṣẹfẹhinti, pẹlu igbagbọ wi pe awọn kan fi n lu jibiti
Nibi ti igbimọ naa ti akọwe agba tẹlẹri lẹka ileeṣẹ to n ri sọrọ eto iṣuna, Ọgbẹni Victor Ọlajọrin to jẹ alaga wọn ti n jabọ lonii Ọjọru, Wẹside, Akeredolu sọ pe iru awọn to n gba owo oṣu naa daju pupọ.
No comments:
Post a Comment