AbdulRazaq b'awọn akọroyin ṣepade, o tu aṣiri awọn akanṣe iṣẹ idagbasoke to fẹẹ da'wọ le ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, August 30, 2022

AbdulRazaq b'awọn akọroyin ṣepade, o tu aṣiri awọn akanṣe iṣẹ idagbasoke to fẹẹ da'wọ le ni Kwara


L'opin ọsẹ to kọja yii ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq b'awọn akọroyin ori ikanni ayelujara ṣe ipade, nibi to ti gbe oṣuba kare fun bi wọn ṣe n ti ijọba rẹ lẹyin nipa kikọ awọn iroyin to n mu idagbasoke ba ipinlẹ naa.
 
Ipade naa ti awọn akọroyin ti ko din ni ọgọrin wa nibẹ lo waye ninu gbọngan ilegbe gomina ipinlẹ naa to wa niluu Ilọrin.
 
Nigba to n sọrọ, AbdulRazaq jẹ ko di mimọ pe inu oko gbese ati ajẹrun loun ba ipinlẹ naa nigba toun gba ọpa aṣẹ, ati pe gbogbo apo owo ipinlẹ naa lo gbẹ fọnfọn.
 
Bakan naa lo fi ye awọn akọroyin pe iwọnba owo to n wọle n'ipinlẹ naa ni iṣakoso oun n lo lati fi mu idagbasoke ba ilu, eyi ti ko ṣẹlẹ ri latigba ti ipinlẹ naa ti wa.
 
O ni ṣe l'awọn ijọba Peoples Democratic Party dabi kokoro ajẹnirun n'igba ti wọn wa ni ijọba fun ọdun mẹrindinlogun, ti ko si si idagbasoke kankan ti wọn le ri tọka si lakoko ijọba wọn.
 
Siwaju si i lo ni gbogbo owo to n wọle sapo ijọba l'awọn oloṣelu to n ṣakoso nigba naa n ko sapo wọn, ti wọn ko si bikita fun idagbasoke araalu, eyi to ni ko bojumu to.

AbdulRazaq, n'igba to n sọ nipa awọn akanṣe iṣẹ to fẹẹ dawọ le, o ni laipẹ, iṣẹ yoo bẹrẹ lori ileeṣẹ ti wọn yoo ti maa ṣe aṣọ, eyi ti wọn yoo gba oṣiṣẹ ti ko din ni ẹgbẹrun meji.

O ni awọn ileeṣẹ miran bi i gbagede ti awọn elere ori itage, onitiata yoo maa lo fun iṣẹ wọn ni ijọba fẹẹ dawọ le, ati pe awọn tun fẹẹ ṣe opopona Adeta Yebumot, Ilesha Gwanara ati Osi-Obbo-Aiyegunle, Afara General Tunde Idiagbon at'awọn miran.
 
Gbogbo awọn iṣẹ yii ni Gomina sọ pe wọn yoo bẹrẹ ki ọdun yii to o pari.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI