Bi ẹ ṣe n ka iroyin yii, inu idunnu ati ayọ l'awọn oṣiṣẹ State Universal Basic Education Board (SUBEB) wa lori bi ijọba ipinle Kwara ṣe san gbese owo oṣu wọn ti iṣakoso ana jẹ silẹ ki wọn to o lọ.
Ọjọ Aje, Mọnde ana ni gomina bu ọwọ lu sisan owo oṣu ajẹẹlẹ naa fun gbogbo awọn oṣiṣẹ SUBEB patapata ti ọrọ naa kan.
A gbọ pe owo oṣu lasan l'awọn oṣiṣẹ SUBEB n gba lakoko ijọba ana to kogba wọle, ti wọn ko si gba awọn ẹtọ to tọ si wọn lori owo oṣu wọn.
Yatọ si eyi, a tun gbọ pe Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tun bu ọwọ lu sisan owo oṣu kẹjọ papọ mọ owo oṣu ajẹẹlẹ naa fun gbogbo awọn oṣiṣẹ patapata.
Alaga ẹgbẹ awọn olukọ n'ipinlẹ naa, Kọmureedi Oyewọle Baṣhir ninu atẹjade to fi sita lo ti f'idi iroyin ọhun mulẹ, nibi to ti n dupẹ lọwọ ijọba fun mimu ileri rẹ ṣẹ fun wọn.
No comments:
Post a Comment