Aderinokun ṣabẹwo si Olowu tuntun l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, August 20, 2022

Aderinokun ṣabẹwo si Olowu tuntun l'Abẹokuta


Akinruyiwa tilu Owu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, Oloye Olumide Aderinokun ti ṣe abẹwo si Olu tilu Owu tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan, Ọba Saka Adeọla Matẹmilọla

Nibi abẹwo naa ni Oloye Aderinokun, ẹni to jẹ oludije s'ipo ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja lati ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP ti sọ pe asiko ti dara ni kabiyesi naa de si.

Ẹni to ṣabẹwo ọhun lonii, ọjọ Abamẹta, Satide jẹ ko di mimọ pe ọba tuntun naa yoo lo iriri rẹ ninu eto ẹkọ, ile aye, iṣẹṣe lati fi mu idagbasoke ba ilu Owu.

Oloye Aderinokun ni ohun to da oun loju ni pe Kabiyesi ti gbaradi lati di ipo ọhun mu ṣinṣin nipa mimu idagbasoke alailẹgbẹ wọlu.

O wa gbadura pe ki kabiyesi naa pẹ laye, ko si lo itẹ naa gbo kọja ohun ti ẹnikẹni le lero lọ.
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI