Baba atọmọ jabọ sinu kọnga, loju ẹsẹ ni wọn ku - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, August 10, 2022

Baba atọmọ jabọ sinu kọnga, loju ẹsẹ ni wọn ku


Kayeefi ni iṣẹlẹ ọhun ṣi n jẹ titi di asiko ti a ṣakojọpọ iroyin yii tan, lori bi baba ati ọmọ rẹ ṣe jabọ sinu kọnga, ti wọn si gbabẹ sọda sọrun aremabọ.
 
Baba naa, Malam Bala, ẹni ọgọta ọdun, ati ọmọ rẹ, Sunusi Bala, toun jẹ ọmọ ọdun marundinlogoji la gbọ pe wọn ku sinu kọnga l'ọjọ Iṣẹgun, Tuside to kọja yii, lagbegbe Sabon Garin Bauchi, ijọba ibilẹ Wudil, ipinlẹ Kano.

A gbọ pe asiko ti awọn mejeeji n gbẹn kọnga naa lọwọ ni wọn jabọ sinu rẹ, ti wọn si padanu ẹmi wọn.
 
Nigba to n sọrọ, Saminu Abdullahi to jẹ alukoro ileeṣẹ panapana ipinlẹ naa sọ pe aarọ ọjọ Iṣẹgun ni iṣẹlẹ ọhun waye, ati pe nnkan bi agogo mọkanla aabọ ni ẹnikan to pe orukọ ara rẹ ni Isma’ila Idris ranṣẹ pe awọn nipa iṣẹlẹ naa.
 
O ni wọn ti gbẹn kọnga ọhun tan, ṣugbọn ti ọmọ naa pada sinu rẹ lati pari gbogbo iṣẹ, nibẹ ni ogiri kọnga naa ti ya bo o. Nibi ti baba naa ti ko sinu rẹ lati doola ẹmi ọmọ rẹ, toun naa fi kagbako nla.
 
Awọn ẹlẹyinju aanu la gbọ pe wọn ko sinu rẹ lati yọ wọn jade, ṣugbọn ti aṣọ ko pada ba ọmọyẹ mọ.
 
Abdullahi jẹ ko ye wa pe awọn ti fa oku awọn mejeeji le ọlọpaa kan to pe ni Insp Felix Gowok ti teṣan ọlọpaa Wudil Model lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI