Ẹ ma ṣe dibo f'awọn adari ti yoo ra ẹri ọkan yin, ti wọn yoo si fi ọjọ ọla yin dokoowo - Goodluck Jonathan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, August 14, 2022

Ẹ ma ṣe dibo f'awọn adari ti yoo ra ẹri ọkan yin, ti wọn yoo si fi ọjọ ọla yin dokoowo - Goodluck Jonathan


Aarẹ ana lorileede yii, Goodluck Ebele Jonathan ti gba gbogbo ọmọ orileede Naijiria lamọran lati ma ṣe dibo f'awọn adari ti yoo ra ẹri ọkan wọn, ti wọn yoo si tun fi ọjọ ọla wọn dokoowo ninu eto oṣelu to n bọ lọna yii.
 
Goodluck Jonathan sọ pe ọpọ awọn oloṣelu lo wa nita lakoko yii to jẹ pe wọn wa ọna lati fi ọjọ iwaju awọn araalu dokoowo nitori iwa imọ tara wọn nikan.
 
Arẹ ana naa lo sọrọ yii lakoko to n sọrọ nibi ayẹyẹ iranti ọdun ti ipapoda Captain Idahosa Okunbo, niluu Abuja l'ọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii
 
“Bi eto idibo ọdun 2023 ṣe n sunmọ etile, a ti gbaradi f'awọn oloṣelu ti wọn ma maa wa ba wa sọrọ, nitori ipo oṣelu ti wọn n wa. Ṣugbọn ero wọn yii ju ti ọdun 2023 lọ.
 
“Amọran mi si awọn ọmọ Naijiria ni wi pe ki wọn farabalẹ lati mọ ibi ti wọn yoo dibo si, ati awọn ti wón yoo dibo wọn fun, ki wọn si rii daju pe wọn dibo wọn sibi to yẹ.

“A ni lati yago kuro ninu eto oṣelu buredi ati bọta, ka si rii pe a ko yan awọn adari ti yoo ra ẹri ọkan wa, ti wọn yoo si tun fi ọjọ ọla awọn ọmọ ati awọn ọmọ-ọmọ wa dokoowo.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI