Ẹ wa gbọ ọna lati dẹkun iṣoro omiyale - Ijọba Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, August 25, 2022

Ẹ wa gbọ ọna lati dẹkun iṣoro omiyale - Ijọba Kwara


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ akoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti gba awọn araalu lamọra lori iṣoro omiyale ati agbara ya ṣọọbu t'awọn eeyan n koju.

Ninu atẹjade ti Kọmiṣanna f'ọrọ eto ayika ati agbegbe, Ọnarebu Rẹmilẹkun Banigbe fi sita laipẹ yii, lo ti sọ pe ki awọn araalu fọwọsowọpọ pẹlu ilana ati agbekalẹ eto ijọba.

O ni bi awọn araalu ba tẹle ilana ati ofin ti ijọba la kalẹ lojuna lati dẹkun iṣoro omiyale, ẹmi ati dukia araalu yoo wa labẹ aabo to peye.
 
Banigbe jẹ ko di mimọ pe bi awọn araalu ba le dẹkun lati maa da ilẹ ati idọti s'awọn ibi ti ko yẹ bii odo, gọta, oju ọna, opopona, ko nii si ohun to n jẹ Omiyale, agbara ya ṣọọbu kankan mọ.

O tẹsiwaju pe dida idọti s'awọn ibi ti ko yẹ lo n fa a ti odo ati gọta fi maa n di pa, ti omi ko si ni raaye jọja lakoko to yẹ.

Bakan naa lo jetko di mimọ pe nipasẹ igbesẹ ara ọtun ti ijọba gbe, lo fa a ti omi ko fi ya mọ lopopona Unity Obbo niluu Ilọrin.
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI