Mi o beere owo to to aadọta biliọnu naira lọwọ Ambọde o - Tinubu pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, August 10, 2022

Mi o beere owo to to aadọta biliọnu naira lọwọ Ambọde o - Tinubu pariwo sita


Gomina tẹlẹri n'ipinlẹ Eko, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu ti sọ pe oun ko beere owo to to aadọta biliọnu naira lati maa gba lọwọ gomina ana n'ipinlẹ naa, Akinwunmi Ambọde lakoko iṣakoso rẹ.
 
Aṣiwaju Tinubu, ẹni to tun jẹ oludije s'ipo aarẹ orileede yii labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC sọ pe irọ to jinna si otitọ otitọ ni iroyin ti wọn n gbe kaakiri naa jẹ.
 
Laipẹ yii ni iroyin kan jade sita wi pe lara awọn idi pataki ti Akinwunmi Ambọde ko ṣe ri tikẹẹti lati pada sipo naa lẹẹkeji gba ni bo ṣe kọ lati san owo naa fun Aṣiwaju Bọla Tinubu.
 
Nigba to n tako iroyin ọhun l'ọjọ Iṣẹgun, Tuside ana, alakoso f'ọrọ eto iroyin ti ẹgbẹ ipolongo fun Tinubu, Bayọ Ọnanuga sọ pe ọga oun ko le beere aduru owo to to bẹẹ.
 
O ni awọn ẹgbẹ kan ti wọn pe ara wọn ni Biafra lo wa nidii iroyin ẹlẹjẹ naa, nitori pe ipinlẹ Eko ko pa owo to to aadọta biliọnu naira lakoko iṣakoso Ambọde gẹgẹ bi i gomina Eko.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI