Tirela Dangote meji to ṣe fayawọ irẹsi wọ Naijiria ti ha si Idiroko - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, August 24, 2022

Tirela Dangote meji to ṣe fayawọ irẹsi wọ Naijiria ti ha si Idiroko


Ọwọ ẹṣọ aṣọbode orileede yii, Nigerian Customs Service (NCS), ti ẹkun kin-in-ni n'ipinlẹ Ogun ti tẹ tirela ileeṣẹ simẹnti Dangote kan ti wọn lo ṣe fayawọ baagi irẹsi mẹtalelọọdunrun wọ orileede Naijiria.
 
Gẹgẹ bi Bamidele Makinde to jẹ alakoso ẹkun naa to wa niluu Idiroko, ijọba ibilẹ Ipokia ṣe ṣalaye f'AWIKONKO, o ni tirela kan lọwọ kọkọ tẹ pẹlu baagi irẹsi igba-din-ni mejidinlọgbọn, ko to di pe ọwọ tẹ tirela miran toun ko irẹsi baagi marundinlọgọrin.
 
Tirela ileeṣẹ Dangote ti nọmba idanimọ rẹ jẹ EKY 971 YE la gbọ pe o ko baagi irẹsi marundinlọgọrin papọ mọ baagi simẹnti, ki aṣiri ma ba a tu, ti ọwọ si tẹ ẹ loju ọna Ibeṣe laarọ ọjọ Aiku, Sannde to kọja.
 
O tun jẹ ko di mimọ pe tirela ti nọmba idanimọ rẹ jẹ BCH 531 XA, ipinlẹ Kano, loun naa ko irẹsi mọ baagi simẹnti, ko to di pe akara tu sepo lagbegbe Lanfẹnwa niluu Abẹokuta laaarọ ana.
 
Nibẹ ni alakoso naa ti sọ pe owo ti ko din ni N13,848,370 l'awọn ti pa ninu ẹru ti wọn ko wọle lọna aitọ l'oṣu keje to kọja yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI