A maa pade nile ẹjọ, Halima to ni Apostle Suleman n ba oun laṣepọ sọrọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, September 30, 2022

A maa pade nile ẹjọ, Halima to ni Apostle Suleman n ba oun laṣepọ sọrọ


Gbajugbaja oṣerebinrin nni, Halima Abubakar ti sọ pe oun ṣetan lati fojuriju pẹlu alaṣẹ ati oludasilẹ Omega Fire Ministries International, to wa niluu Auchi, ipinlẹ Ẹdo, Apostle Johnson Suleman niwaju ile ẹjọ.

Apostle Johnson Suleman lo gbe Halima lọ sile ẹjọ, lori ẹsun to fi kan an wi pe awọn jọ ni Ibalopọ lọpọ igba.

Halima laipẹ yii ti sọ ọ lori ikanni ayelujara wi pe oun pẹlu gbajumọ pasitọ naa jọ wa ninu ibadọrẹ tipẹtipẹ, ti awọn si ni Ibalopọ rẹpẹtẹ.

Suleman naa si ti tako ọrọ ọhun pe irọ nla to jinna si otitọ ni, nitori pe awọn kan mọra lasan ni, kii ṣe bii ti Ibalopọ, eyi gan-an lo mu ki Suleman gba ile ẹjọ lọ.

Halima tun fi ẹsun kan Suleman wi pe ọkunrin naa lọ san owo fun awọn akọroyin ori ayelujara lati fi ba oun lorukọ jẹ.

Suleman, ninu ẹsun to pe lo ti sọ pe Halima ba oun lorukọ jẹ, o si tun n kọ oríṣiríṣi ọrọ buruku to n tabuku ba orukọ oun sita.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI