Awakọ to lu jibiti miliọnu mẹtadinlogun aabọ owo dọla dero atimọle EFCC l'Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, September 16, 2022

Awakọ to lu jibiti miliọnu mẹtadinlogun aabọ owo dọla dero atimọle EFCC l'Ekoo


Ọpọ awọn to ri baale ile kan, Ọlabanji Aluko ti wọn f'ẹsun jibiti owo to din diẹ ni miliọnu mejidinlogun owo dọla, iyẹn $17.5m ni wọn n ṣiye meji pe ko le ṣe iru nnkan bẹẹ, ṣugbọn ti ajọ EFCC sọ pe ogbologbo ni nidii iṣẹ alọnilọwọ gba.
 
A gbọ pe Ọjọru, Wẹsidee, to kọja yii lọwọ tẹ Aluko, ẹni to loun yan iṣẹ ọkọ wiwa laayo n'ipinlẹ Eko. Ile ounjẹ igbalode kan to gbajumọ daadaa lagbegbe Falọmọ, Ikoyi, n'ipinlẹ naa la gbọ pe ọwọ palaba ẹ ti segi.
 
Ibi ipade kan to gbe kalẹ pẹlu ẹni to lu ni jibiti owo owo naa, ajagunfẹyinti Col. Remi Abdulrahman Adeyemo lọwọ ti tẹ ẹ.

Wọn ni Adeyẹmọ to wa fi ẹsun kan ọkunrin naa sọ pe ẹnikan to pe ara rẹ ni Ojo lo pe oun lori foonu lọjọ kan wi pe awọn ti mọ ara wọn tipẹ.
 
Ẹni naa sọ pe ọkan lara awọn oun ati iyawo ẹ ni gbolohun asọ, ti ọrọ naa si ti de ile ẹjọ. O lọmọ oun fẹẹ tete ta ile to ni danu, ko to di pe ijọba gba ile rẹ fun iyawo to fẹ naa.
 
O sọ pe owo naa l'awọn nilo lati fi ta ile ọhun to wa nilẹ Amẹrika, ko ma ba a padanu titi lai sọwọ obinrin. O ni orukọ ileeṣẹ kan ni wọn yoo fi gbe owo ọhun gba ori omi, ileeṣẹ naa to pe ni Loomis International, ni New York lo sọ pe wọn maa fi gbe e wa fun.
 
Lẹyin eyi lo tun sọ pe ẹlomiran tun pe ounlori foonu wi pe oun yoo ni lati san ẹgbẹrun mẹfa din ni ọọdunrun owo dọla, $5,700, lati fi pari iṣẹ ti yoo fi gba owo naa.
 
Nibẹ ni wọn sọ pe Adeyẹmọ ti fura pe ọrọ naa ko jẹ otitọ, to si gba ọdọ ajọ EFCC to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lọ lati fi to wọn leti.
 
Ibi ti wọn fi ipade si la gbọ pe ọwọ ti tẹ ọkunrin naa pẹlu awọn ayederu iwe to fẹẹ fi lu Adeyẹmọ ni jibiti.

Ni bayii, ajọ EFCC ti fi da gbogbo agbaye loju wi pe ọkunrin yii yoo foju ba ile ẹjọ lati gba idajọ to tọ sii lori ẹsun jibiti ti wọn fi kan an.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI